Faith Adebọla, Eko
Ọwọ awọn agbofinro ti ba awọn afurasi ọdaran mẹta kan ti wọn ko aṣọ idanimọ oṣiṣẹ amuṣeya (Taskforce) ileeṣẹ ijọba to n mu awọn to ba rufin imọtoto ati ẹsun akanṣe (Lagos State Environmental and Special Offences Unit), sọrun, ti wọn n ṣe bii oṣiṣẹ ijọba tootọ, bẹẹ niṣe ni wọn n lu awọn onimọto ni jibiti, ti wọn n fi wọn pawo sapo ara wọn.
Orukọ awọn mẹtẹẹta tọwọ palaba wọn segi lọsan-an Ọjọruu, Wẹsidee yii, ni Samuel Oyegbule, ẹni ọdun mejilelaaadọta, Ọlayiwọla Thomas, ẹni ọdun mẹtalelaaadọta ati Kọla Taiwo, toun jẹ ẹni ọdun mẹtadinlaaadọta.
Ba a ṣe gbọ, wọn lo ti pẹ tawọn mẹtẹẹta yii ti n da awọn onimọto atawọn ọlọkada laamu lagbegbe Oshodi, wọn maa n sọ pe Taskforce lawọn, pe ijọba ibilẹ Oṣodi/Isọlọ ni wọn pin awọn si.
Boya aṣiri wọn iba ma tu bi ko ba ṣe owo ijẹkujẹ to ti mọ wọn lara, awọn meji kan ni wọn mu lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, lori ba ta ko wọn.
Alaga ileeṣẹ tawọn afurasi naa purọ mọ fi jẹun, CSP Shọla Jẹjẹloye, sọ pe o ti pẹ tawọn ti n gbọ finrinfinrin nipa iwa jibiti tawọn araabi yii n hu, ṣugbọn awọn o tete ri wọn mu. O lawọn meji kan ni wọn kọwe ẹsun nipa awọn afurasi yii lọjọ Tusidee.
Ọkan ninu wọn ti ko fẹẹ darukọ ara ẹ sọ pe jẹẹjẹ loun n wa mọto oun lọ, oun si duro nibi ti ina to n dari ọkọ ti tan pupa, ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ foun bawọn onijibiti ṣe waa kan gilaasi ọkọ ayọkẹlẹ oun, ti wọn ni koun yi gilaasi mọto naa walẹ, wọn si sọ pe oun ti rufin irinna lori iduro toun wa ọhun.
O ni niṣe ni wọn fagidi wọ oun lọ si sẹkiteria kansu Oṣodi-Isọlọ, wọn si fipa gba ẹgbẹrun mẹẹẹdọgbọn naira lọwọ oun ki wọn too foun ati mọto silẹ.
Ẹni keji to ko sakolo wọn lọjọ kan naa sọ pe niṣe loun n ja ero to haaya ọkọ oun silẹ lẹgbẹẹ titi, o ni ibi toun duro si ko ṣediwọ kankan fun ọkọ tabi awọn eeyan to n kọja o, ṣugbọn ganboro lawọn ayederu oṣiṣẹ ijọba yii yọ soun, wọn loun lufin. O ni gbogbo alaye toun ṣe ni o wọ wọn leti, wọn ṣaa fipa wọ oun lọ si kọrọ kan ninu ọgba kansu kan naa, nibi ti wọn ko awọn ọkọ oriṣiiriṣii si, wọn si gba ẹgbẹrun mẹẹẹdọgbọn naira oun naa.
Jẹjẹloye ni bawọn ti wọn mu yii ṣe fọrọ naa to awọn leti ti wọn si ṣalaye lẹkun-un-rẹrẹ biṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ sinu lẹta wọn lo jẹ kawọn tete ri wọn mu, awọn si ri i pe wọn ki i ṣe oṣiṣẹ ijọba rara, niṣe ni wọn lọọ ṣe ayederu aṣọ idanimọ awọn, pẹlu awọn risiiti irọ ti wọn n ja fawọn eeyan.
Ṣa, awọn mẹtẹẹta yii ti wa lakata awọn ọlọpaa nibi ti wọn ti n fẹnu fẹra bii abẹbẹ, ti wọn n ṣalaye ara wọn.