Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti bẹrẹ iwadii lori awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn pa ọmọkunrin kan niluu Oṣogbo lopin ọsẹ yii lẹyin ti wọn ja awọn to n ṣe POS meji lole.
ALAROYE gbọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun abala mi-in ni ọmọkunrin ti wọn pa yii, ṣe ni wọn si fọ okuta mọ ọn lori titi ti ẹmi fi bọ lara rẹ.
Awọn gende mẹfa ni wọn ṣiṣẹ naa, ọkada meji ni wọn si gbe lọ si adugbo ti ọmokunrin naa n gbe, bi oun naa ṣe ri wọn lo n sa lọ, ṣugbọn wọn le e ba, wọn si fi okuta nla fọ ọ lori.
Gẹgẹ bi awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe sọ, bi wọn ṣe fọ okuta mọ ọn lori, ti wọn si ri i pe ẹmi ti bọ lara rẹ, ni wọn bọ sori ọkada mejeeji ti wọn gbe debẹ, ti wọn si lọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni Ọja-Ọba lawọn eeyan ọhun ti kọkọ ja awọn oni POS meji lole ki wọn too lọọ pa ọmọkunrin naa.
Ọpalọla ṣalaye pe wọn gba ẹgbẹrun lọna ọgọfa naira lọwọ Ọgbẹni Oyedeji, nigba ti wọn gba ẹgbẹrun lọna igba naira lọwọ Ọgbẹni Abdulafeez.
O ni awọn ko ti i mọ orukọ ọmọkunrin ti wọn pa ọhun, ṣugbọn wọn kọ 777 si igbaaya rẹ, eleyii to fi han pe ọmọ ẹgbẹ okunkun ni.
O fi kun ọrọ rẹ pe iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa ati pe laipẹ lọwọ yoo tẹ awọn to ṣiṣẹ laabi naa.