Ajinigbe ku iku ojiji l’Ọdẹda, lẹni ti wọn ji gbe ba dominira

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ọsan gangan laago mejila ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrin, ọsu kẹfa yii, ni DPO teṣan Bode Olude, l’Abẹokuta, gba ipe pe awọn darandaran ajinigbe ti ji dẹrẹba kan gbe l’Ọdẹda o. Abajade ipe naa ni iku ọkan lara awọn Fulani to ji dẹrẹba gbe ọhun. Awọn agbofinro yinbọn mọ ọn lẹsẹ, nibi ti wọn ti n gbe e lọ sọsibitu lo ti dakẹ.

Ohun to ṣẹlẹ gan-an gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa Ogun, ṣe wi ni pe agbegbe kan ti wọn n pe ni Molọgẹdẹ, nijọba ibilẹ Ọdẹda, ni awọn ajinigbe ti ki dẹrẹba kan to n wa ọkọ tipa mọlẹ, ti wọn gbe e wọgbo lọ. Afurasi darandaran ni wọn pe awọn ajinigbe naa.

DPO Bode Olude, DSP Durojaye Rotimi, pe awọn ikọ rẹ, awọn ọlọdẹ, awọn Fijilante So–Safe atawọn ọlọpaa lati awọn teṣan to wa nitosi, ni wọn ba gba Ọdẹda lọ.

Wọn wọgbo titi ki wọn too ri awọn ajinigbe naa, nigba ti wọn si foju kan ara wọn, awọn ajinigbe doju ibọn kọ awọn ọlọpaa atawọn agbofinro yooku, awọn iyẹn naa da tiwọn pada, lojo ibọn ba n rọ ninu igbo.

Oyeyẹmi sọ pe nibi ti wọn ti n yinbọn mọra wọn naa nibọn ti ba ajinigbe kan lẹsẹ, o ba awọn mi-in ninu wọn naa, ṣugbọn wọn sa lọ pẹlu ọgbẹ ibọn lara wọn. Bẹẹ lawọn ẹṣọ alaabo yii gba ọkunrin ti wọn ji gbe naa silẹ lọwọ wọn.

Eyi tibọn ba lawọn agbonfinro gbe kuro ninu igbo lati tọju ẹ lọsibitu ko le pada waa jẹjọ, ṣugbọn nibi ti wọn ti n gbe e lọ sọsibitu naa lo ti ku patapata.

Ibọn kan ni wọn ri gba lọwọ awọn ajinigbe naa ki wọn too na papa bora.

Leave a Reply