Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Fidelis Francis, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, to n gbe nipinlẹ Cross River, ni Calabar, ati Lukman Jimọh, ẹni ogoji ọdun, to n gbe l’Akurẹ, nipinlẹ Ondo, ti wa lahaamọ ọlọpaa nipinlẹ Ogun bayii, ohun to si fa a naa ni ti ole ti wọn waa ja ni Ṣọọṣi Ridiimu ni Ṣagamu, lọjọ keje, oṣu kẹfa yii.
Ni nnkan bii aago meji oru ọjọ naa ni DPO teṣan ọlọpaa Ṣagamu, CSP Okiki Agunbiade, gba ipe, pe awọn ole n fọ́ ṣọọṣi naa to wa ni GRA, Ṣagamu, lọwọ.
Nigba tawọn ọlọpaa yoo fi debẹ ṣa, awọn ole naa ti pitu ọwọ wọn tan, wọn si ti fo fẹnsi sa lọ.
Nibi tawọn ọlọpaa ti n wa awọn igbo to wa nitosi ni wọn ti ri mọto ayọkẹlẹ Lexus kan ti nọmba ẹ jẹ KJA 469 EP. Itosi ṣọọṣi naa ni wọn paaki mọto yii si, awọn ọlọpaa si woye pe o ṣee ṣe ko jẹ awọn ole naa lo gbe e sibẹ, ni wọn ba sa sibi kan, wọn n duro de ẹni ti yoo waa gbe ọkọ naa.
Lẹyin wakati marun-un ti wọn ti fara pamọ, Francis ati Lukman de, wọn fẹẹ maa gbe mọto naa lọ lawọn ọlọpaa yọ si wọn lojiji, ni wọn ba mu wọn.
DSP Abimbọla Oyeyẹmi to fiṣẹlẹ yii to wa leti ṣalaye pe awọn ọlọpaa yẹ inu mọto Lexus naa wo, wọn si ba irin meji to jẹ iru rẹ wa ninu ṣọọṣi ti wọn ti jale ninu mọto yii. Eyi tun mu ki ara fu awọn ọlọpaa si wọn, wọn si ko wọn lọ sinu ṣọọṣi naa.
Aṣe awodi oke awọn ole yii ko mọ pe ara ilẹ n wo oun ni. Aṣe kamẹra wa ni ṣọọṣi naa to n ka gbogbo bi wọn ṣe n jale ọhun silẹ, ati gbogbo ohun ti wọn ṣe pata.
Fidio ti kamẹra ya ni wọn gbe si i fawọn ẹlẹgiri meji naa pe ki wọn maa wo o, ni wọn ba rira wọn kedere bi wọn ṣe n pitu buruku ninu ile Oluwa.
Nigba ti wọn ti n wo ara wọn bii iran ni wọn ko ti le parọ mọ, wọn jẹwọ pe awọn lawọn wọ ṣọọṣi jale loru loootọ, bo ṣe ri ni kamẹra ṣe ka a silẹ yẹn. Wọn jẹwọ ilu ti wọn ti wa pẹlu, nigba naa lawọn ọlọpaa mọ pe Calabar ni Francis ti waa jale ni Ṣagamu, Lukman si ti Akurẹ wa.
CP Edward Ajogun gboriyin fawọn ọlọpaa to ṣiṣẹ ọtẹlẹmuyẹ naa, o ni ki wọn ri i pe wọn gbe awọn ole meji naa lọ si kootu laipẹ.