NDLEA mu awọn meji to n ta egboogi oloro fawọn agbebọn ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Ajọ to n gbogun ti asilo oogun ati egbogi oloro (NDLEA) ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti mu Martins Okwor Ejio ati Bala Mohammed ni opopona marosẹ, Okoolowo, niluu Ilọrin si Jẹbba, nipinlẹ Kwara, fẹsun pe wọn gbe egboogi oloro.

Ninu Mọto ( Hiace bus) ti nọmba iforukọ silẹ rẹ jẹ Niger 14B-40 NG. Ni wọn ti gba wọn mu pẹlu egboogi oloro ti ko din ni iwọn 24.45 kilograamu.

Nigba ti wọn fi ọrọ wa wọn lẹnu wo, ni wọn jẹwọ pe awọn agbebọn lawọn maa n lọọ ta a fun ninu igbo kan to wa ni agbegbe Gwanda, nijọba ibilẹ Shiroro, nipinlẹ Niger.

Wọn tẹsiwaju pe ọja kan wa ninu igbo naa to gbaju-gbaja tawọn agbebọn ti maa n ṣe kara-kata egbogi oloro ati awọn nnkan miiran to fara pẹ ẹ.

Ajọ (NDLEA) ti waa gbe awọn afurasi naa lọ si olu ileesẹ wọn to wa ni Ilọrin fun ẹkunrẹrẹ iwadii.

 

 

Leave a Reply