Lati sami ayẹyẹ ọdun ijọba awa-ara-wa toloyinbo n pe ni Democracy, ijọba apapọ ti kede ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrinla, oṣu kẹfa yii, gẹgẹ bii ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ
Minisita fun eto abẹle nilẹ wa, Ọgbẹni Rauf Aregbeṣọla, lo gbe ikede naa sita lorukọ ijọba apapọ ilẹ wa. O ki awọn ọmọ Naijiria ku ọdun, o si rọ wọn ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu ijọba to wa lode yii ninu akitiyan rẹ lati ri i pe ilẹ wa wa ni iṣọkan ati ipo to dara.
Bẹẹ lo rọ awọn eeyan lati yago fun ipongbẹ fun ki Naijiria pin.