Faith Adebọla
Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu, ti kede pe eto ti n lọ labẹnu, iṣẹ naa ko si ni i pẹ pari, ti yoo mu ki ikọ alaabo Amọtẹkun to wa nilẹ Yoruba lọwọ yii para da bii ọga, ti wọn yoo si di ọlọpaa ipinlẹ.
Akeredolu sọrọ yii nibi asọye pataki ti wọn fi sọri ayẹyẹ ajọdun ‘June 12’ ti wọn tun n pe ni ayajọ iṣejọba demokiresi nilẹ wa, eyi to waye niluu Akurẹ, lọjọ Abamẹta, Satide yii. Ọgbẹni Fẹmi Aboriṣade lo ṣoju fun gomina yii nibẹ.
Gomina naa ni ohun to le jẹ ki iṣejọba tẹsiwaju, ko si nitumọ, ni bi awọn ipele iṣakoso kọọkan ba ni ọlọpaa tirẹ, ki ijọba apapọ ni ọlọpaa tiwọn, ki ipinlẹ kọọkan lawọn ọlọpaa ipinlẹ, kọlọpaa ibilẹ naa si wa fawọn ijọba ibilẹ.
Akeredolu ni: Niṣe lo yẹ ki ipinlẹ kọọkan maa pinnu iye ijọba ibilẹ ti wọn fẹ, ki eto iṣakoso baa le dele-doko, kawọn oṣiṣẹ ọba si le ba ohun to n ṣẹlẹ nipinlẹ ati ibilẹ kọọkan mu, tori iru ẹka iṣẹ ọba ati oṣiṣẹ ọba ti ipinlẹ ati ijọba ibilẹ kan maa nilo le yatọ gedengbe si ti omiiran. Bi ipinlẹ kan ba ṣe n pawo wọle si naa lo yẹ ko han lara awọn ijọba ibilẹ ti wọn ba ni, ki i ṣe eyi ti a n lo bayii, to jẹ ijọba apapọ lo n pin owo fun ijọba ibilẹ ati ipinlẹ kaakiri.
Gomina yẹ ko jẹ alakooso ijọba to maa maa ṣe ifẹ awọn araalu ẹ loju mejeeji ni, ofin yẹ ko faaye gba wọn lati lo owo ti wọn ba n pa wọle nipinlẹ kaluku fun anfaani awọn ti wọn dibo fun un ni, ki i ṣe eyi ti apaṣẹ waa kan tun maa wa nibomi-in ti wọn tun gbọdọ gbọran si lẹnu lọran-anyan, ko si yẹ ki ijọba apapọ maa da si awọn ọrọ abẹle ipinlẹ ati ibilẹ kọọkan, ko yẹ ko kan wọn rara.”
Akeredolu ko fọrọ sabẹ ahọn sọ nigba to sọ pe niṣe nireti ati agbọkanle tawọn eeyan ni lasiko ti wọn n dibo ‘June 12’, lọdun 1993 pada ja si pabo pẹlu bi orileede yii ti ri lasiko yii, ṣugbọn o loun ko fara mọ ipinya tabi iyapa, tori iyẹn kọ lọna abayọ si iṣoro to wa nilẹ yii.
O ni afi tijọba ba ṣetan lati ṣatunṣe sawọn ohun to wọ ninu iwe ofin ilẹ wa, ti wọn si fun ọrọ aabo ni akiyesi pataki, igba naa ni ẹkọ to yẹ ka ri kọ ninu ibo ọdun ‘June 12’ ti a n ṣe ajọdun rẹ yii maa too so eso rere.