Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Gbajugbaja akọrin ẹmi nni, Tọpẹ Alabi, tun ti n gbọ ọrọ buruku lẹnu awọn eeyan lori ayelujara bayii, bawọn eeyan si ṣe n ri fidio to ti fẹnu abuku kan Adeyinka Alaṣeyọri, ọmọbinrin to kọrin ‘Oniduuro mi ẹ ṣeun’ ni wọn tun n bu Tọpẹ si i. Wọn ni ko gbe ẹnu rẹ sọhun-un, ko jọ pe o wa ok rara.
Oju agbo kan ni Tọpẹ Alabi ti bẹrẹ ọrọ yii lasiko to n kọrin, niṣe lo si da orin ọhun duro to bẹrẹ si i sọrọ pe,
“Ẹ wo aduru ohun ti Ọlọrun jẹ yẹn, ẹ wo aduru ohun ti Ọlọrun ṣe, iyẹn lẹni kan waa sọ pe Oniduuro mi ẹ ṣeun. Ọlọrun ki i ṣe Oniduuro temi. Ọlọrun kọja Oniduuro sir, o kọja Oniduuro.
“Emi naa laiki orin yẹn, ọjọ ti mo fẹẹ kọ ọ bayii, Ẹmi mimọ ni gbẹnu ẹ sọhun-un. O kọja Oniduuro.
“Ki i ṣe pe boya eeyan fi n sọ pe orin kan o daa, rara. Ta a ba ti gba orin ninu ẹmi, o ni awọn aṣaro teeyan maa n ṣe pẹlu Ẹmi mimọ ko too gbe e jade. Ai jẹ bẹẹ, to ba jẹ bo ṣe n gbe e wa leeyan ṣe n sọ ọ ni, onikaluku o kan maa sọsọkusọ ni.
“O ti fun wa lọpọlọ, a maa jẹ ẹ, a maa gbe e mi, a ṣẹṣẹ maa waa gbe e pada’’ Bẹẹ ni Tọpẹ Alabi wi.
Ṣugbọn bawọn eeyan ṣe n wo fidio naa lori Fesibuuku ni wọn n kọ ọrọ buruku ranṣẹ si Iya Ayọmikun, iyẹn Tọpẹ Alabi. Wọn ni oun funra rẹ lo n sọ isọkusọ, o si yẹ ko gbe ẹnu rẹ sọhun-un ni.
Funmi Yinka-Ọlajide, ọkan ninu awọn to binu si Tọpẹ, kọ ọrọ tiẹ pe, ‘Aunti Tọpẹ, ṣe ẹ wa ok? Ki lo ṣe orin yẹn? Ọlọrun ni Oniduuro temi. Jọwọ sọ fun mi bo o ṣe n ba Ẹmi mimọ sọrọ. Ẹ maa wa ‘alright ma, isọkusọ lẹ n sọ jade lẹnu’
Ọmọ Jesu Ọmọ Jesu toun naa jẹ ọkan ninu awọn to kọ ọrọ sabẹ fidio yii sọ pe ki Tọpẹ Alabi tilẹkun ẹnu rẹ nla yẹn. O ni bawo ni yoo ṣe ri lara tiẹ naa bẹni kan ba n fẹnu abuku kan orin to kọ.
O ni Tọpẹ ati Wolii Ajanaku nkọ, niṣe kọ ni Tọpẹ n forin yin ọkunrin naa, to sọ ọ di oriṣa akunlẹbọ, abi o ro pe awọn eeyan ko ri oun nigba yẹn ni. O ni ki Tọpẹ yee ba orin awọn eeyan jẹ, oun fẹran orin tiẹ naa, ṣugbọn ko tẹ ẹ jẹẹjẹ.
Ẹlomi-in torukọ tiẹ n jẹ Ọla Ọmọ Ọla, ni ki Tọpẹ yee jowu.
O ni nigba ti Tọpẹ sọ pe ọti Jesu n pa oun, ko ma sẹni kan to ba a wi fun un. O ni ko fi ọmọbinrin kekere to n kọrin rẹ jẹẹjẹ naa lọrun silẹ. Awọn Mama Bọla Aarẹ ṣaa gba oun Tọpẹ naa wọle nigba to bẹrẹ orin, ki lo de toun ko fẹ ki ọmọ kekere dide.
Funkẹ Afọlabi sọ pe oun fẹran Tọpẹ Alabi ju gbogbo ohun to n ṣe yii lọ. O ni to ba tiẹ jẹ loootọ lo fẹẹ pe ọmọbinrin to kọrin naa si akiyesi, ṣe nita gbangba bii eyi lo ti yẹ ko ṣe e ni. Paapaa, nigba ti ọmọbinrin naa ko si nibi ti Tọpẹ ti n sọrọ yii. Funkẹ ni afi k’Ọlọrun ṣaanu awọn Kristẹni o.
Oliver John ni Tọpẹ Alabi ni lati lọọ kọ ede oyinbo daadaa ko si mọ itumọ oniduuro ti Adeyinka wi.
O ni opurọ aye ni Tọpẹ Alabi, Ẹmi mimọ wo lo ni ko gbẹnu sọhun-un. O ni awọn eeyan yii kan n purọ tan awọn eeyan jẹ ni.
Bẹẹ lawọn eeyan n kọ oriṣiiriṣii ọrọ sabẹ fidio yii, ṣugbọn ko sẹni kan to gbe lẹyin Tọpẹ, gbogbo wọn n sọ pe ọrọ alailoye lori lo sọ ni, ko si yẹ kiru ọrọ bẹẹ ti ẹnu rẹ jade si akọrin Kristẹni bii tiẹ rara.
Adeyinka Alaṣeyọri lọmọbinrin naa to kọrin Oniduuro mi yii, orin naa si ṣe daadaa nitori ọpọ eeyan lo tẹwọ gba a ti wọn n kọ ọ kiri.
Ọna ti Adeyinka n gba kọrin rẹ tun maa n jẹ kawọn eeyan fẹran rẹ, oun naa lo kọrin ‘Aaye ọpẹ yọ’ tawọn eeyan n kọ kiri bayii lai fi ti ẹsin ṣe. Ohun ti Tọpẹ Alabi sọ nipa orin rẹ yii tun fi han pe aye fẹran ọmọbinrin naa, wọn si n gbeja rẹ bii ẹni ti Ọlọrun funra rẹ yọnu si, to si ti ṣaṣeyọri bii orukọ rẹ ni.