Florence Babaṣọla
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ ọmọkunrin kan ti wọn n pe ni Akin, ẹni to gbe ọrẹbinrin rẹ lọ si Apomu lọsẹ to kọja, to si kun un si wẹwẹ lẹyin to ba a sun tan.
Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Wale Ọlọkọde, sọ fun ALAROYE nirọlẹọjọ Abamẹta, Satide, lọwọ tẹ Akin niluu Ibadan to sa lọ lẹyin iṣẹ iwadii to lagbara.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja, ni awọn ọlọpaa ṣafihan Kabiru Oyeduntan, ẹni ọdun mọkandinlogoji, lori ẹsun pe o lẹdi apo pọ mọ Akin lati pa ọrẹbinrin rẹ.
Yara Kabiru niluu Apomu ni Akin gbe ọmọbinrin naa lọ lọjọ Tọsidee to kọja yii, lẹyin to ba a sun tan lo fọwọ fun un lọrun pa pẹlu iranlọwọ Kabiru.
Kabiru ṣalaye pe lẹyin ti ẹmi bọ lara rẹ ni Akin mu ọbẹ nla kan, to si bẹrẹ si i ge e si wẹwẹ, o ni awọn ọlọpaa ko ri Akin mu titi to fi sa lọ nitori wọn ko tẹle imọran toun fun wọn lori bi ọwọ ṣe le tẹ ẹ.
Amọ ṣa, Ọlọkọde ṣeleri lọjọ naa pe ko si ibi ti Akin le wọle si ti ọwọ ko ni i tẹ ẹ. Idi niyẹn to fi sọ pẹlu ayọ nirọlẹ ọjọ Satide pe ọwọ ti tẹ Akin, ati pe yoo foju bale-ẹjọ laipẹ lati sọ ohun to ri lọbẹ to fi waro ọwọ.