Faith Adebọla
Idajọ oju-ẹsẹ lawọn ọdọ tinu n bi ṣe fun afurasi ajinigbe kan tọwọ wọn tẹ lagbegbe Orile-Agege, nipinlẹ Eko, lopin ọsẹ to kọja yii, niṣe ni wọn ti ọkunrin naa mọnu ọkọ ayọkẹlẹ to gbe wa, wọn si dana sun un mọbẹ.
Irọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, la gbọ pe iṣẹlẹ naa waye, ko si sẹni to mọ orukọ ọkunrin ti wọn fẹsun kan pe gbọmọgbọmọ ni yii.
Ninu fọran fidio to n ja ranyin lori atẹ ayelujara, ẹyin tọkunrin naa ti jo tan ni wọn wọ oku rẹ bọ silẹ ninu mọto alawọ buluu ti wọn ti sun ọhun, wọn tun la pako mọ-ọn lori, wọn si tuka.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ ọhun, awọn yoo si kede abọ iwadii awọn to ba ya.
Bakan naa ni wọn kilọ lodi si ṣiṣẹ idajọ bii eyi fawọn afurasi ọdaran, tori iru ṣeria adabọwọ ara-ẹni bẹẹ lodi sofin ilẹ wa.