Faith Adebọla, Eko
Ṣe wọn ni igba ko lọ bii orere, asiko itura ati aye gbẹdẹmukẹ dopin fun Ọgbẹni Francis Atuche, ọga agba banki PHB tẹlẹri, latari bile-ẹjọ giga kan ṣe sọ pe ọkunrin naa jẹbi ẹsun kiko owo awọn kọsitọma rẹ jẹ, ti wọn si dajọ ẹwọn ọdun mẹfa fun un.
Bakan naa nile-ẹjọ sọ ekeji rẹ, Ugo Anyanwu, to jẹ ọga lẹkaa iṣiro owo fun banki naa tẹlẹ sẹwọn, ọdun mẹrin pere ni wọn ni koun fi jura.
Ile-ẹjọ giga ipinlẹ Eko to fikalẹ siluu Ikẹja, ni igbẹjọ naa ti waye l’Ọjọruu, Wẹsidee yii, ẹsun mẹtadinlọgbọn ni wọn ka sawọn mejeeji lẹsẹ, ile-ẹjọ si ni wọn jẹbi ẹsun mọkanlelogun ninu ẹ.
Ajọ to n gbogun ti jibiti lilu, iwa ajẹbanu ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC) lo wọ awọn ọdaran mejeeji yii lọ ile-ẹjọ lẹyin ti wọn lawọn ti ṣewadii, wọn si ri i pe ọwọ wọn ko mọ nidii owo olowo ti wọn ṣe yala yolo lasiko ti wọn fi ṣakoso banki PHB, ti orukọ rẹ ti yipada si Keystone Bank bayii.
Ṣaaju ni EFCC ti ṣalaye pe laarin oṣu kọkanla, ọdun 2007, si oṣu kẹrin, ọdun 2008, biliọnu mẹẹẹdọgbọn naira, ati miliọnu meje lo dawati ninu koto ikowosi banki ọhun.
EFCC ni iwadii awọn fihan pe niṣe ni awọn ọdaran mejeeji yii n lo ipo ati aṣẹ wọn lati lu ibi iṣẹ wọn ni jibiti, wọn jale, wọn si n lo awọn akaunti to jẹ tiyawo ati mọlẹbi wọn mi-in lati gbọn owo banki naa lọ.
Wọn tun ni oriṣiiriṣii ẹyawo ni wọn ṣe ni bonkẹlẹ laarin ara wọn, ti wọn ko tẹle ilana owo yiya ni banki, bẹẹ owo gọbọi ni wọn gba jade, ti ko si si adapada awọn owo naa.
Agbefọba Kẹmi Pinheiro ta ko awijare olujẹjọ pe awọn ko ji owo naa, awọn ya a ni, ati pe ohun to ba wu awọn lawọn le lo ẹyawo naa fun.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Lateefat Okunnu, ni ahesọ ati awawi ni awọn olujẹjọ naa n sọ lori ẹsun ki-in-ni titi de ikọkanla, ẹsun kẹrinla si ogun ati awọn ẹsun mẹta mi-in, nitori naa ile-ẹjọ naa da wọn lẹbi, o ni ki wọn Atuche lọọ ṣewọn ọdun mẹfa fun ẹsun kọọkan, ki Ugo si lọọ ṣẹwọn ọdun mẹrin fun ẹsun kọọkan, bo tilẹ jẹ pe wọn maa ṣewọn naa papọ ni.
Adajọ Abilekọ Lateefat ni oun ko ri idi to lẹsẹ nilẹ lati da awọn iyawo wọn lẹbi fun bawọn ọkọ wọn ṣe n taari owo sinu akaunti wọn, o ni awọn obinrin naa ko jẹbi, o si da wọn silẹ pe ki wọn maa lọ ile wọn lalaafia.
Bakan naa ni Adajọ yii paṣẹ pe ki ijọba gbẹsẹ le gbogbo dukia ti awọn ọdaran naa ba ni, ki wọn si ta wọn lati fi da gbese ti wọn jẹ ati ole ti wọn ja pada. O ni eyi yoo jẹ arikọgbọn fawọn ti wọn ba n lo ipo ati agbara wọn lati lu jibiti.