Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ọwọ ẹka ọlọpaa to wa fun ipe pajawiri ati titani lolobo nipinlẹ Ekiti ti tẹ awọn akẹkọọ mẹrinla kan ti wọn jẹ ọmọleewe Crown Polythechnic, Odo-Ekiti, nipinlẹ Ekiti, wọn ni wọn ji akẹkọọ ẹgbẹ wọn torukọ ẹ n je Akiọde Akinyẹmi, gbe.
Ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹfa yii, lawọn ajinigbe kan ṣadeede wọle awọn akẹkọọ, ti wọn ji Akiọde Akinyẹmi gbe lọ sinu igbo. Aṣe awọn akẹkọọ bii tiẹ lo ṣiṣẹ naa.
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, ṣalaye pe ni deede aago mẹwaa alẹ lawọn akẹkọọ naa ti wọn dihamọra bii ẹni to n lọ soju ogun, ya wọ ile akẹkọọ yii, ti wọn si gbe e lọ.
Alukoro tẹsiwaju pe lẹyin ọjọ keji lawọn ajinigbe ọhun fi foonu Akinyẹmi pe awọn obi ẹ, ni wọn ba n beere fun miliọnu meji ati ẹgbẹrun lọna igba naira gẹgẹ bii owo itusilẹ rẹ. Awọn obi ọmọ naa beere pe nibo lawọn yoo sanwo naa si, awọn ajinigbe wọnyi si fi nọmba ile ifowopamọ mẹjọ ọtọọtọ ṣọwọ si wọn lati sanwo ọhun si.
Abutu fi kun un pe bi idunaa-dura yii ṣe n lọ lọwọ lawọn obi akẹkọọ ti wọn ji gbe yii ti ta awọn ọlọpaa lolobo, awọn agbofinro si sọ fun wọn pe ki wọn lọọ sanwo naa. Ṣugbọn lọgan ni wọn bẹrẹ itọpinpin lori ọrọ naa, abajade rẹ si ni bọwọ ṣe ba awọn akẹkọọ mẹrinla ti wọn pe orukọ wọn ni; Afọlabi Ọlamide Lekan, Peter Adeyẹmi, Abiọdun Oluwaṣeun, ‘Bamidele Emmanuel, Adewumi Ṣọla, Adeṣuyi Adeyẹye Ọlarewaju, David Daniel, Damilare Yusuf, Ọlaṣile Hassan, Jesse Obinna, Mohanye Samuel, Olugbade Timilẹyin, Ọlamide Temilade ati Blessing Ọmọtuyi. Ọkunrin ni gbogbo wọn.
Ọga ọlọpaa sọ pe gbogbo awọn tawọn fi panpẹ ofin mu naa ni wọn ti jẹwọ pe loootọ lawọn ṣẹ ẹṣẹ naa, bẹẹ ni wọn si jẹwọ ni gbangba pe miliọnu meji ati ẹgbẹrun lọna igba naira lawọn gba lọwọ awọn obi Akinyẹmi, awọn si ti pin in kawọn too fi i silẹ.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Tunde Mọbayọ, fi aidunnu rẹ han lori ọrọ naa. O ṣapejuwe ẹ gẹgẹ bii iwa to buru laarin awọn akẹkọọ ilu naa. Ọga ọlọpaa yii rọ awọn eeyan awujọ pe ki wọn maa ta awọn lolobo bi wọn ba kofiiri nnkan ifura.