Faith Adebọla
Bo tilẹ jẹ pe Ẹgbẹ Ilana Yoruba ti kọkọ sọ pe pẹlu ohun to ṣẹlẹ, iyẹn bi awọn kan ṣe ya wọ ile Sunday Igboho, ti wọn paayan, ti wọn si tun da gbogbo ile rẹ ru, ti wọn ba mọto rẹ jẹ lọjọ kin-in-ni, oṣu yii, iwọde to yẹ ko waye naa ṣi maa waye. Ṣugbọn ni bayii, ajijagbara naa ti sọ pe awọn ti da iwọde naa duro, ko ni i waye mọ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹta, oṣu ta a wa yii.
Igboho sọrọ naa fun ileeṣẹ iroyin BBC Pidgin ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii. O ni awọn ti da ipade naa duro di ọjọ mi-in, ọjọọre.
Tẹ o ba gbagbe, oru Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni awọn kan tẹnikẹni ko ti i mọ ya wọ ile ọkunrin naa niluu Ibadan. Wọn pa eeyan meji, bẹẹ ni wọn ji awọn kan gbe lọ, ti wọn si ba mọto ati ile rẹ jẹ.