Adefunke Adebiyi
Kọmandi ọlọpaa nipinlẹ Ogun ti fi orukọ ọkunrin kan, Adewumi Lawal, sita bayii pe awọn n wa a lati waa ṣalaye ara ẹ lori ẹsun ifipabanilopọ. Ọmọbinrin ọmọ ọdun mẹrindinlogun (16), ni wọn lo wọle tọ lọjọ kẹfa, oṣu kẹfa, ọdun yii, to fipa ba a lo pọ nile wọn to wa n’Itele, Ado-Odo/ Ọta, nipinlẹ Ogun.
Tulaasi ni Lawal ti wọn ni onimọ-ẹrọ ni, fi wọle awọn ọmọ naa lọ lasiko ti iya wọn ko si nile. Niṣe lo gbe bẹnṣi, to la mọ ọn ilẹkun ile wọn, to si wọle. Nigba naa lo ki ọmọbinrin ọhun mọlẹ, to fi aṣọ di i lẹnu (bọmọ naa ṣe ṣalaye), to si gba ibale rẹ pẹlu ibasun to le.
Ọjọ keji ọjọ naa lo ti sa lọ nile, wọn ko si ti i ri i titi dasiko yii. Wọn lo ni oun ko ṣe nnkan kan fọmọ naa, oun ba a nibi ti aburo rẹ ti n ba a sun ni, o si ro pe oun yoo sọrọ naa fun iya wọn, iyẹn lo ṣe parọ mọ oun.
Lawal niyawo nile, ọdun keji to si ti tirafu ree. Ọjọ keji to de lati ilu to lọ ni wọn lo ba ọmọde sun yii, bo si ti di ọjọ kẹta rẹ lo tun ti sa lọ nile.
DSP Oyeyẹmi ti ni afi ko tete waa fa ara ẹ kalẹ, nitori orukọ ẹ ti wọnu iwe awọn tijọba n wa. O lawọn mọ pe Pọtakọọtu lo wa, ọwọ awọn yoo too ba a ṣinkun