.Florence Babaṣọla
Aarẹ tuntun fun ẹgbẹ Kiriji nilẹ Yoruba (Kiriji Heritage Defenders), Oloye Alebioṣu Kalaowo, ti sọ pe itakun to ba ni ki erin iran Yoruba ma goke lorileede yii, toun-terin ni yoo jọ lọ, nitori ko si nnkan to le da a duro mọ, ilẹ Yoruba yoo gba ominira lọwọ awọn amunisin ti wọn wa nipo adari.
O kilọ fun gbogbo awọn ti wọn n dunkooko mọ awọn ajijagbara ilẹ Yoruba lati tun ero wọn pa, ki wọn si mọ pe ko si bi wọn ṣe le halẹ tabi gbogun to, ilẹ Yoruba yoo de ilẹ ileri.
Ni kete ti wọn bura fun Alebioṣu tan nibi ti ogun Kiriji pari si niluu Imẹsi-ile, nipinlẹ Ọṣun, lo ṣalaye pe ẹgbẹ naa yoo ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ikọ agbofinro ati awọn ti ibilẹ lati pese aabo to daju fun gbogbo iran Yoruba lorileede yii.
Kalaowo sọ pe bi awọn agbebọn ṣe sọ ilẹ Yoruba di ibuba lati huwa ibi, ti wọn n paayan, ti wọn si n fipa ba awọn obinrin lo pọ, ti agbara awọn agbofinro ko si ka wọn lo jẹ ki awọn eeyan dide lati kin ijọba lọwọ.
Gẹgẹ bo ṣe wi, “Ẹmi awọn baba-nla wa ti wọn ti jagun sẹyin nilẹ Yoruba lo parada di awọn bii Sunday Igboho, Gani Adams atawọn aṣaaju ti wọn n ja fun ominira ilẹ Yoruba, bi wọn ba si gbogun ti ẹni kan ṣoṣo ninu wọn, iyẹn ko le da irẹwẹsi si ọkan awọn to ku.
“Gbogbo wa la wa pẹlu Igboho, ogun kankan ko si le bori rẹ. Gbogbo ipa wa la maa sa lati ri i pe aabo to peye wa ni ilẹ Yoruba, abẹ alakalẹ ofin orileede yii la o si ti maa ṣe ohunkohun ti a ba n ṣe”
Bakan naa ni Alebioṣu fun gbogbo awọn ti wọn ni nnkan oṣin nilẹ Yoruba ni gbedeke oṣu kan pere lati ṣe ile fun awọn nnkan ọsin wọn, ki wọn si dẹkun fifi nnkan ọsin jẹko kaakiri gẹgẹ bii aṣẹ ti awọn gomina ilẹ Yoruba pa.
Ṣaaju ninu ọrọ rẹ, alakooso agba fun Kiriji Heritage Defenders, Dokita Ademọla Ẹkundayọ, ṣalaye pe awọn oloye tuntun ti Ọba Ogboni Agbaye, Ọba Adetoyeṣe Ọlakisan, ṣẹṣẹ fi jẹ ọhun yoo ṣiṣẹ lati ri i pe eto aabo kẹsẹ jari nilẹ Yoruba.