Sunday Igboho pe awọn DSS lẹjọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nitori bi wọn ṣe fi tipatipa wọnu ile ẹ loruganjọ, ti wọn si paayan meji ninu awọn to n gbe pẹlu ẹ, ti wọn tun ko ọpọlọpọ dukia lọ, ajafẹtọọ ọmọ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ, ti pe ileeṣẹ ọlọpaa- inu, DSS, lẹjọ.

Miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹta Naira (N500,000) lọkunrin ti gbogbo aye mọ si Sunday Igboho yii rọ ile-ẹjọ lati ba oun gba lọwọ awọn agbofinro naa gẹgẹ bii owo itanran fawọn dukia oun ti wọn bajẹ nigba ti wọn fi tipa tikuuku wọle oun lọganjọ oru bíi igba ti awọn adigunjale wọle onile.

Bakan naa lo ni ki wọn san owo to jọju fun idile awọn eeyan meji ti wọn pa nipakupa lasiko ikọlu ojiji ọhun.

Yatọ si gbogbo eyi, Sunday Igboho ni ki ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ kọwe ẹbẹ fun aforiji lọwọ oun lati sọ fun gbogbo aye pe awọn gba pe awọn jẹbi oun Igboho Ooṣa lori iwa ti ko bofin mu ti wọn hu sí oun yii.

Ninu atẹjade ti agbẹjọro rẹ, Amofin-Agba Yọmi Alliyu, fi ṣọwọ sawọn oniroyin n’Ibadan, o ni awọn DSS ba awọn dukia, to fi mọ mọto olowo iyebiye to wa ninu ọgba ile oun jẹ.

Agbẹjọro naa fi kun un pe gbogbo ibọn ti awọn  agbofinro sọ pe awọn ba nile onibaara oun ki i ṣe tiẹ rara, awọn funra wọn ni wọn mọ ibi tí wọn ti ri awọn ibọn naa.

O ni lati bíi ogun ọdun sẹyin ti gbogbo ayé tí n gbọ orukọ gbajumọ eeyan ti wọn n pe ni Sunday Igboho, ko sẹni to le sọ pe oun ka ibọn mọ ọn lọwọ ri nitori ọkunrin naa ki i gbebọn rin.

Bakan naa lo fọ ajafẹtọọ Yoruba naa mọ kuro ninu ẹsun ipinnu iwa ọdaran ti wọn fi kan an, o ni onibaara oun ko figba kankan pinnu lati huwa idaluru kankan

 

Leave a Reply