Stephen Ajagbe, Ilorin
L’Ọjọbọ, Tọsidee, oni yii, ni ile-ẹjọ giga kan ni ipinlẹ Kwara ti fun ijọba laṣẹ lati kọ ile sori ilẹ ti ẹbi awọn Saraki kọ Ile-Arugbo si. Adajọ Abiọdun Adebara tun paṣẹ fawọn lati san ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira fawọn ti wọn pe lẹjọ, iyẹn Gomina Kwara, Adajọ agba, ile-igbimọ aṣofin ati ileeṣẹ ijọba to n mojuto ọrọ ilẹ, fun fifi akoko wọn ṣofo, ati bi agbẹjọro wọn, Akin Onigbinde, ṣe kọ lati yọju sile-ẹjọ.
Bakan naa, Ile-ẹjọ ni wọn yoo tun san ẹgbẹrun lọ́nà aadọta naira fun ileeṣẹ ọlọpaa, nitori bi wọn ṣe n fa ẹjọ naa nilẹ, nipa bi wọn ṣe kọ lati wa sile-ẹjọ fun ọpọlọpọ igba tẹjọ naa ti n waye.
Onigbinde kọ lẹta ranṣẹ sile-ẹjọ pe ara oun ko ya, o si fi akọsilẹ awọn dokita ti i lẹyin. O ni wọn ni oun gbọdọ fun ara nisinmi, ki oun si wa lori ibusun nileewosan lati ọjọ kẹta si ikẹwaa, oṣu yii. Ṣaaju nile-ẹjọ ti n sun ẹjọ naa siwaju fun ọpọlọpọ igba. Nibi ijokoo to waye lọjọ kẹjọ, oṣu keje, Onigbinde funra rẹ rọ ile-ẹjọ lati sun un si ọjọ kejilelogun, oṣu keje, ọdun yii, ṣugbọn nigba to maa di ọjọ naa, o tun gbe awawi mi-in kalẹ. Eyi lo mu ki wọn sun ijokoo mi-in si oni, Ọjọbọ, ọjọ kẹfa, oṣu kẹjọ, sibẹ wọn ko tun ri i.
Olootu ati kọmiṣanna fun eto idajọ, Salman Jawondo, to ṣoju ijọba, ni olupẹjọ naa kan n mọ-ọn-mọ fi akoko ile-ẹjọ ṣofo lasan ni, o rọ ile-ẹjọ lati da ẹjọ naa nu. Ileeṣẹ ọlọpaa to jẹ olujẹjọ karun-un ti wọn pe lẹjọ naa gba aba Jawondo wọle, wọn ni ki adajọ fagi le ẹjọ naa, nitori o ti fi han pe awọn olupẹjọ ko ni nnkan i ṣe. Adajọ waa sun ẹjọ ọhun si ọjọ kẹtalelogun, ati kẹrinlelogun, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, lati gba agbẹjọro olupẹjọ laaye lati tẹsiwaju ninu ẹjọ naa.
Ileeṣẹ Asa Investment Limited, to jẹ ti Oloogbe Abubakar Oluṣọla Saraki lo wọ ijọba Kwara lọ sile-ẹjọ lori bi wọn ṣe wo Ile-Arugbo, loṣu kin-in-ni, ọdun yii.