Faith Adebọla, Eko
Ọkan lara awọn aṣaaju ẹgbẹ Oodua Peoples Congress (OPC) ni agbegbe Ibarapa ati Abuja, Ọgbẹni Oluwọle Adedeji, ti sọ pe bi awọn agbofinro ṣe lọọ mu ajijagbara ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ, ti wọn n pe ni Sunday Igboho ko tọna, ko si le mu ki ariwo ibeere fun idasilẹ Orileede Oodua, iyẹn Yoruba Nation, lọ silẹ, kaka bẹẹ, niṣe lo maa tubọ mu ko le si i.
Nigba to n ba ALAROYE sọrọ lori aago laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, nipa iṣẹlẹ ọhun, Adedeji ni ohun tijọba ko mọ ni pe ijangbara ti Sunday Igboho n ṣe ki i ṣe tara rẹ nikan rara, ọgọọrọ awọn alatilẹyin ati ajijangbara ni wọn wa labẹlẹ, ti wọn si n ṣatilẹyin to ju ti Sunday Igboho lọ.
“Sunda Igboho nijọba n ri, iyẹn lo fi jẹ pe oun ni wọn fẹju mọ, wọn o mọ pe ki i ṣe Sunday Igboho nikan lo n sọrọ, aimọye awọn to lowo, ti wọn si lagbara ju Igboho lọ, ti wọn si ti pinnu lori Yoruba Nation yii.
Mimu ti wọn mu un yii ko le bomi tutu sọkan wa, ipinnu yii ki i ṣe ọrọ Sunday Igboho, ọrọ Yoruba ni, ki wọn too le pana ariwo Yoruba Nation, gbogbo Yoruba ni ki wọn mu.
Ati pe kin ni Sunday Igboho ṣe funjọba gan-an ti wọn fi n dọdẹ ẹmi ẹ kiri, ki ni wọn fẹẹ lo ṣe fawọn, ki wọn bọ sita sọ faraye? Ṣe ẹṣẹ ni keeyan sọ ohun to n fẹ, kawọn ololufẹ ẹ si sọpọọti ẹ ni?”
Adeyemọ pari ọrọ rẹ pe “niṣe ni ki Sunday mọkan le, ko ma bẹru rara, ko si ohun ti wọn le fi i ṣe. Ọlọrun lo n lo o lasiko yii, awọn alalẹ Yoruba ko sun, wọn si wa lẹyin ẹ. Ohun to n ja fun ki i ṣe tara ẹ nikan. Orileede Yoruba maa ṣẹlẹ, boya wọn fẹ tabi wọn kọ.”