Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde tun ti ṣepade bonkẹlẹ mi-in pẹlu Dokita Olusẹgun Mimiko nile rẹ to wa niluu Ondo l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ ta a wa yii.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, abẹwo ẹlẹẹkeji ti Makinde ṣe ọhun ni lati bẹ ẹ pe ko le ṣatilẹyin fun Eyitayọ Jẹgẹdẹ to jẹ oludije ẹgbẹ PDP ninu eto idibo to n bọ lọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun yii. Ọjọ kẹrindinlọgbọn, osu kẹfa, ọdun yii, ni Makinde ṣabẹwo akọkọ, idi to si tori ẹ wa nigba naa ko yatọ si eyi to tun waa ṣe bayii.
Odidi ọdun mẹjọ ni Jẹgẹdẹ fi jẹ kọmisanna feto idajọ labẹ iṣejọba Mimiko, oun naa lo si fa a kalẹ gẹgẹ bii oludije labẹ asia ẹgbẹ PDP lasiko eto idibo to waye lọdun 2016. Ọrọ ibo ọdun naa lọhun-un lo pada da aarin ọga ati ọmọọsẹ yii ru latari ẹsun tawọn ọmọlẹyin Jẹgẹdẹ fi kan Mimiko pe o dalẹ eeyan awọn, to si lọọ ṣiṣẹ fun Gomina Rotimi Akeredolu to jẹ ọrẹ rẹ, leyii to mu ko jawe olubori.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, ni Jẹgẹdẹ funra rẹ ṣabẹwo si ile Mimiko niluu Ondo, nibi tawọn mejeeji ti ṣepade, bo tilẹ jẹ pe ko ṣeni to mọ ohun ti wọn jọ sọrọ le lori.