Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ọdọmọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogun kan ti wọn pe orukọ re ni Jide ku lojiji, nigba ti awọn mi-in tun fara pa nibi ija kan to waye lasiko eto idibo abẹle to waye nipinlẹ Ekiti lọjọ Abamẹta, Satide.
Wọọdu kẹwa, ni agbegbe GRA, niṣẹlẹ naa ti waye niluu Ado-Ekiti.
Alaye ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa to wa nibi iṣẹlẹ yii ṣe fun akọroyin wa ni pe ọmọkunrin naa ti mu ọti ati egboogi oloro yo, lẹyin to si ti wa lẹrẹ lo bẹrẹ ariyanjiyan pẹlu awọn ẹlẹgbẹ rẹ miiran to wa ni ibudo idibo naa, eyi to pada di ija nla.
Wọn ni niṣe ni Jide pa igo ọti to gbe wa si ibi eto idibo naa, to si fẹẹ gun ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ toun na wa nibẹ.
Lẹyin iṣẹju diẹ la gbọ pe ẹnikan gun Jide nikun, ti wọn si sare gbe e lọ si ileewosan, nibi tawọn dokita ti fidi rẹ mulẹ pe o ti jade laye.
Aṣoju ALAROYE to lọ kakiri ilu Ado-Ekiti ati awọn ilu miiran ti eto naa ti waye sọ pe niṣe ni awọn alatilẹyin Gomina Fayẹmi fẹnu ko si pe ki wọn fa ẹni kan ṣoṣo kalẹ ni agbegbe kọọkan eyi ti wọn n pe ni (Consensus candidate). Ṣugbọn awọn alatilẹyin Oludamọran Aarẹ Buhari lori eto oṣelu, Ọgbẹni Babafẹmi Ojudu, yari pe awon ko ni i gba igbesẹ bẹẹ.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe loootọ ni eeyan kan ku nigba ti ija bẹ silẹ nibi ti wọn ti n ṣe eto idibo naa. “A ṣẹṣẹ gba ipe pajawiri lati ọdọ DPO to wa ni agbegbe naa ni, Alaga kansu ijọba ibilẹ Ado-Ekiti, Iyaafin Ọmọtunde Fajuyi naa ti pe wa.
“A ti bẹrẹ iwadii to daju lori iṣẹlẹ naa, wọn si ti gbe oku ọmọdekunrin naa lọ si ile igbokuu-pamọ si to jẹ ti ijọba ni Ado-Ekiti.
Nigba ta a beere boya wọn ti ri ẹnikẹni mu lori iku oloogbe naa, Alukoro ni awọn ko ti i ri ẹnikẹni mu, o ṣeleri pe oun yoo pada pe akọroyin wa lati fun un labọ bi awọn ba ri ẹnikẹni mu.