Faith Adebola
Ọjọ kẹrin, oṣu kẹjọ yii, ni ile-ẹjọ sun igbẹjọ awọn ọmọlẹyin Sunday Igboho ti wọn ko nile rẹ lọjọ kin-in-ni, oṣu keje, ọdun yii, ti awọn ọtẹlẹmuyẹ ya wọ ile naa, ti wọn ko awọn mejila lọ, ti wọn si paayan meji.
Ni ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni wọn ko awọn eeyan naa wa si ile-ẹjọ giga kan niluu Abuja.
Ṣugbọn wahala ti agbẹjọro awọn olujẹjọ, Pẹlumi Ọlajẹngbesi, ati ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ n fa mọra wọn lọwọ ni pe ọtọ ni orukọ to wa lọwọ awọn ọtẹlẹmuyẹ, ọtọ ni orukọ ti lọọya mu wa. Eyi ni awọn ọtelemuyẹ yii kọkọ purọ mọ ti wọn fi ni awọn ko le yọnda ki wọn ko wọn wa sile-ẹjọ gẹgẹ bii aṣẹ ti kootu pa nitori ko si orukọ awọn eeyan ti wọn n da ni akata awọn.
Lasiko ti igbẹjọ naa waye lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, mẹjọ ninu awọn eeyan naa ni awọn DSS ko wa sile-ẹjọ.
Eyi lo mu ki Adajọ Obiora Egwuatu fun lọọya naa lanfaani lati ṣe atunṣe si awọn orukọ naa. Ọjọ kẹrin, oṣu kẹjọ, ọdun yii, ni wọn sun igbẹjọ mi-in si.