Tirela ja wọle n’Ijẹbu-Ode, o pa iya atọmọ pẹlu ọlọkada

Adefunkẹ Adebiyi,  Abẹokuta

Omijẹ n bọ loju awọn eeyan, kaluku n ṣedaro ikunlẹ abiyamọ ni lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ keji, oṣu kẹjọ yii, nigba ti tirela kan to ko okuta padanu ijanu ẹ, to ja wọle n’Ijẹbu-Ode, to si pa obinrin kan atọmọ rẹ to gbe dani, bẹẹ lo ran ọkunrin ọlọkada kan naa lọ sọrun ọsan gangan.

Ohun ti awọn tiṣẹlẹ yii ṣoju wọn sọ ni pe ere buruku ni tirela to ko okuta naa n sa, wọn lo n bọ lati Agọ-Iwoye, o n lọ s’Ijẹbu-Ode. Itosi Lagos Garage, lo de  ti tirela ti ko ni nọmba naa fi padanu ijanu ẹ, to si ṣe bẹẹ wọ ile to wa lọọọkan rẹ lọ.

Obinrin alabiamọ kan to gbe ọmọ to n tọ lọwọ dani lo kọkọ kọ lu, o run wọn mọbẹ, awọn mejeeji si ku loju-ẹsẹ. Ọlọkada kan naa ti wọn ni o n bọ jẹẹjẹ rẹ lati ọna Ayegbami naa ko agbako ọkọ yii, o si run un pa.

Ohun to dun ọpọ eeyan ni pe niṣe ni dẹrẹba to wa tirela naa sa lọ pẹlu ọmọ ẹyin ọkọ rẹ, ẹnikan ko ri wọn mu lẹyin aburu ti wọn ṣe.

Lasiko ti a n kọ iroyin yii lọwọ, bi awọn ajọ TRACE yoo ṣe gbe tirela naa kuro ninu ile to wo si ni wọn n ṣe lọwọ, bẹẹ ni wọn n gbiyanju lati mọ boya ko tun seeyan mi-in ti kinni ọhun kan, ko ma lọọ jẹ pe oku ṣi wa labẹ ile to wọ lọ naa.

Lẹẹkan si i, TRACE tun kilọ fawọn awakọ, awọn onitirela ti ijanu wọn ki i yee sọnu yii, pe ki wọn yee fi tiwọn ko ba alaiṣẹ, ki wọn ni iwa ọmọluabi loju popo, nitori ẹmi ti wọn fi n ṣofo yii ṣẹ n pọ ju, wọn ni ki gbogbo onimọto pata maa ṣọra ṣe .

Leave a Reply