Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Adajọ-fẹyinti Akin Ọladimeji to jẹ alaga igbimọ ti Gomina Oyetọla gbe kalẹ lati gbọ oniruuru ẹsun to ṣu yọ nipa awọn agbofinro lẹyin wahala ifẹhonu han EndSars ti sọ pe pupọ ninu wahala to n dabaru orileede bayii lo jẹ afọwọfa awọn agbofinro.
Nitori idi eyi, o ni o yẹ kijọba bẹrẹ si i ṣayẹwo ẹnikẹni to ba fẹẹ darapọ mọ iṣẹ ọlọpaa lorileede yii lati le mọ boya wọn ni arun ọpọlọ tabi bẹẹ kọ.
Nigba to n sọrọ lasiko to gbe akọsilẹ abajade iwadii igbimọ to dari fun gomina lo ti ṣalaye pe atunṣe gbọdọ de ba ilana bi wọn ṣe n gba awọn eeyan si iṣẹ ọlọpaa ati iṣẹ agbofinro to ku lorileede yii.
O ni iriri oun lasiko ijokoo igbimọ naa fi han pe ọpọlọpọ iṣẹlẹ ni ko yẹ ko yọri si wahala ifẹmiṣofo tabi biba dukia jẹ bi ki i ba ṣe ọwọ ti awọn agbofinro ilẹ wa fi n mu wọn.
Ọladimeji fi kun ọrọ rẹ pe iwe ẹsun oriṣii mẹrinlelọgbọn (34) ni igbimọ naa gba, wọn taari mẹtala sigbo fun awọn idi kan, wọn fagi le meji, bẹẹ ni wọn ṣayẹwo lori ẹsun mọkanlelogun to ṣẹku.
O sọ siwaju pe tijọba ba le tẹle gbogbo imọran tigbimọ oun kọ sinu iwe naa, yoo yanju ọpọlọpọ wahala ati idaloro ti ihuwasi awọn agbofinro ti da silẹ nipinlẹ Ọṣun ati ni orileede Naijiria.
Ninu ọrọ idupẹ rẹ, Oyetọla gboriyin fun awọn ọmọ igbimọ naa fun bi wọn ṣe ṣa gbogbo ipa wọn lati tu awọn ọkan to ti n fi ọpọ ọdun banujẹ ninu.
O ni igbimọ naa ti fun awọn araalu ti awọn agbofinro ti yanjẹ lọna kan tabi omiran ni ireti pe idajọ ododo ṣi daju.
Oyetọla waa fi da gbogbo araalu loju pe ijọba oun yoo ṣiṣẹ tọ imọran awọn ọmọ igbimọ naa laipẹ.