Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Lẹyin ọjọ kẹta ti awọn ajinigbe ji odidi mọlẹbi kan gbe l’Ekiti, ti wọn si pa ẹni kan lara wọn, wọn tun ti ji agbẹ mi-in, baba ẹni ọdun mọkanlelọgọrin kan, Suyi Bamisaye, gbe nipinlẹ naa.
Baba yii ni awọn agbebọn yii sadeede wọ inu oko rẹ to wa ni agbegbe Oke-Ijẹbu, niluu Ikọle-Ekiti, nijọba ibilẹ Ikọle, ti wọn ki i mọlẹ, ti wọn si gbe e lọ si ibi ti ẹnikẹn ko ti i mọ bayii.
Awọn mọlẹbi baba yii ṣalaye fun akọroyin wa pe aarọ kutu ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni baba naa kuro nile pẹlu alupupu rẹ, to si dagbere fun awọn pe oun n lọ soko.
Nigba to di aago mẹfa irọlẹ ti wọn ko gburoo rẹ ni wọn gbiyanju lati pe ẹrọ ilewọ rẹ, ṣugbọn ko lọ.
ALAROYE gbọ pe nigba ti aago mẹjọ alẹ lu ni ẹnikan pe ọkan ninu awọn mọlẹbi rẹ, to si sọ fun wọn pe ki wọn san aadọta miliọnu naira ki baba agbẹ naa too le gba iyọnda.
Iṣẹlẹ yii la gbọ pe o ti da jinnijinni ati ibẹru si awọn eeyan agbegbe naa lara. Ipaya ibi ti wọn ti fẹẹ ri owo ti awọn eeyan naa n beere fun si ti mu wọn. Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe awọn ti bẹrẹ igbesẹ lati gba agbẹ naa silẹ.
O ni awọn ẹṣọ Amọtẹkun ati awọn ọdẹ ibilẹ ti darapọ mọ awọn ọlọpaa lati wo gbogbo igbo to wa ni agbegbe naa, o ṣe ileri pe awọn yoo gba agbe naa jade.