Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹwaa, oṣu kẹjọ yii, lọwọ awọn agbofinro ipinlẹ Ogun ba ọmọkunrin Fulani kekere yii pẹlu ibọn AK 47 lọwọ rẹ, ninu igbo kan ti wọn n pe ni Ọha, n’Iwoye -Ketu, nijọba ibilẹ Imẹkọ-Afọn, nipinlẹ Ogun.
Mohammed lọmọdekunrin naa pe orukọ ara ẹ, darandaran lo ni oun n ṣe. Ṣugbọn ko ri alaye ṣe fun ohun ti Fulani nilo ibọn fun to ba n daran, n lawọn ọlọpaa fijilante So-Safe atawọn ọlọdẹ ibilẹ ti wọn ri i ninu igbo naa ba yaa mu un.
Awọn kan ni wọn ta DPO Imẹkọ lolobo pe awọn ri awọn omọde Fúlàní ọkunrin meji kan ninu igbo Ọha ti wọn gbebọn dani.
Eyi lo mu awọn ọlọpaa atawọn ma-jẹ-o-bajẹ mi-in wọnu igbo naa lọ, ti wọn si bẹrẹ si i fọgbo kiri lati ri awọn ọmọde agbebọn yii mu.
Lẹyin ọpọlọpọ wakati ti wọn ti wọgbo naa kiri ni wọn ri Muhammed yii mu nibi to sa pamọ si toun tibọn to ju ọjọ ori rẹ lọ.
Gẹgẹ bawọn ọlọpaa ṣe wi, wọn ni gbogbo oye lo foju han pe ọkan ninu awọn ikọ ajinigbe to n da agbegbe naa laamu lọmọ yii yoo jẹ.
Wọn ti gbe ọmọde naa lọ sẹka itọpinpin, bẹẹ lawọn ọlọpaa ṣi n wa inu igbo naa lati ri awọn yooku rẹ.