Faith Adebọla
Ọga ọgba ileeṣẹ iroyin jade Tribune, Ọgbẹni Edward Dickson, ti ṣapejuwe ipo ti awọn oniroyin ati ileeṣẹ agberoyinjade wa lasiko yii bii igba teeyan ba lugbadi arun aṣekupani Korona to n ja ranyin kari aye lasiko yii, o ni bii igba ti ẹka naa wa nipo ẹlẹgẹ, lẹsẹ-kan-aye ẹsẹ-kan-ọrun ni.
O ni ipenija nla to n koju iṣẹ naa ti mu ko tubọ ṣoro gidi lati ṣaṣejere nidii ẹ, ati pe bi nnkan ṣe ri latẹyinwa titi dasiko yii, wahala nla ni keeyan too le kaju inawo to wa nidii ẹ, ka ma ṣẹṣẹ sọ ti pe konitọhun rọwọ yọ.
Lasiko to n kopa ninu ifọrọwerọ ori redio ilu Ibadan kan lọkunrin naa ti sọ pe: “Ta a ba ni ka sododo, ki Korona too de ni Korona ti mu ẹka ileeṣẹ iroyin, to jẹ abẹ itọju ba-a-ku ba-a-ye lo wa. Ni pato, ogun gidi ni lati le gbe iweeroyin Tribune ti mo wa jade looojumọ, ipenija nla si ni pẹlu. Okoowo to ṣoro lati ṣalaye ni, keeyan too le loye ẹ, aa pẹ. Mo le fi gbogbo ẹnu sọ ọ fun yin pe iweeroyin kọọkan ti a n ta lori atẹ yẹn, gbese lo ba de. Ẹ si le lọ sawọn ileeṣẹ iweeroyin kaakiri, ẹ maa ri i pe ọkan naa ni kan-un, bakan naa lọmọ ṣe ori ni.
Awa ti Ọlọrun fi sipo akoso ileeṣẹ yii la mọ ohun ti oju wa n ri, to jẹ pe gbogbo ohun to ba gba la maa n fun un lati le ri i pe iweeroyin jade, iso inu ẹku la maa n fi ọrọ ṣe lọpọ igba. Ileeṣẹ agberoyinjade ko gbọdọ ku, a o gbọdọ jẹ ko parun, tori to ba run, awujọ wa ti wọ wahala niyẹn.
Idi si ni pe ileeṣẹ iroyin kọọkan lo ni ojuṣe labẹ ofin lati maa ṣọ bi nnkan ṣe n lọ si lorileede ati lawujọ, ka si maa pese isọfunni to yẹ faraalu ati funjọba. Tori ẹ, ko si alakooso ileeṣẹ iweeroyin kan to maa fẹ ko parun.
Ọga agba naa sọ pe gbogbo iṣapa to yẹ lawọn to wa lẹka ileeṣẹ iroyin gbọdọ ṣe lati ma ṣe sọreti nu, tori ipa ribiribi ni wọn n ko lawujọ kọọkan.