Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọga agba ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku, EFCC, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Usman Muktar, ti ṣe abẹwo si Kọmiṣanna ọlọpaa tuntun ni Kwara, Ọgbẹni Amienbo Tuesday Assayomo, ni olu ileeṣẹ wọn, nibi to ti beere fun ifọwọsowọpọ ileeṣẹ ọlọpaa, ki wọn le jọ gbogun ti awọn to n lu jibiti lori ẹrọ ayelujara ati awọn iwa ibajẹ mi-in ni ipinlẹ ọhun.
Muktar ni idi pataki ti oun fi ṣe abẹwo ọhun ni pe oun n fẹ ajọṣepọ to lọọrin laarin ajọ EFCC ati ileeṣẹ ọlọpaa, ki awọn le jọ ṣe aseyọri ti alakan n ṣepo, nibi gbigbogun ti lilu jibiti ati awọn iwa ibajẹ miiran nipinlẹ Kwara, o tẹsiwaju pe oun gbọ pe kọmisanna tuntun ọhun de si ipinlẹ Kwara, to si ṣe pataki ki ajọ EFCC ki i kaabọ, kawọn mọ ara awọn, ki ajọṣepọ to muna doko le wa laarin ileeṣẹ mejeeji.
Kọmisanna Assayomo dupẹ lọwọ ọga agba EFCC, fun abẹwo to ṣe si ileeṣẹ ọlọpaa, bakan naa lo lu ajọ naa lọgọ ẹnu fun iṣẹ takun-takun ti wọn n ṣe lati ri i pe iwa ibajẹ dopin, o waa jẹẹjẹ pe gbogbo agbara ti ileeṣẹ ọlọpaa ba ni, ni yoo fi satilẹyin, ti wọn yoo si fọwọsowọpọ pẹlu ajọ ọhun, ti iwa ibajẹ yoo fi rodo lọọ mu’mi patapata ni Kwara.