Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Awọn igbimọ to n ri si ọrọ ọba ati oye jijẹ nile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun ro pe Goriọla Hassan tawọn ni ko yee pe ara ẹ lọba ilu Imobi-Ijẹbu yoo waa jẹ ipe awọn lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹjọ yii ni, ṣugbọn ọkunrin naa ko yọju si wọn rara ti wọn fi pari ipade. Awọn baalẹ atawọn alatilẹyin rẹ to wa si sọ pe bile n jo, bole n ja, ọba tawọn ni Goriọla Hassan n ṣe.
Ṣe lọsẹ to kọja lọhun-un ni ile naa ti ni bi Goriọla ko ba waa jẹ ipe awọn lori bo ṣe n pe ara ẹ lọba Imobi, tawọn kan si ti kọwe pe ipo naa ko tọ si i, awọn yoo fọlọpaa mu un ni.
Ṣugbọn nigba ti ko tun yọju yii,niṣe ni awọn aṣofin tun ranṣẹ pe e nigba kẹta, wọn ni ko wa lọjọ keji, oṣu kẹsan-an, laago mọkanla aarọ, ko waa rojọ ẹnu rẹ fawọn.
Ṣugbọn awọn oloye Imobi ti wọn jẹ alatilẹyin ọkunrin yii ba awọn akọroyin sọrọ lọjọ Iṣẹgun naa ninu ọgba awọn aṣofin Ogun, wọn ṣalaye bo ṣe jẹ pe Goriọla lọba tawọn fẹ, ati pe awọn to kọwe sileegbimọ kan n fakooko wọn ṣofo ni.
Oloye Ọmọtayọ Bello, ẹni ti ṣe Oloye Oluti, ti ilu Uba, nibi ti wọn ti bi Adeniyi Goriọla Hassan, ṣalaye pe ko si ootọ kankan ninu iroyin ti wọn n gbe kiri pe Goriọla Hassan ki i ṣe ọmọ bibi ilu Uba, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ijẹbu.
Oloye Ọmọtayọ sọ pe, “Baba to bi baba ẹ ni ọkunrin akọkọ ti wọn bi niluu Uba, ọmọ ọba ni lagboole Orẹsanya, niluu Uba, Ọṣẹyiku lorukọ baba to bi baba ẹ niluu Uba.
“Goriọla Hassan ta a yan gẹgẹ bii ọba ta a fẹẹ fi jẹ maa n wa sile deede, nigba ti ọrọ ọba si ṣẹlẹ, ọba Uba ti i ṣe ibi tawọn baba nla ẹ tẹdo si lo sọ pe oun fẹẹ jẹ, o kan lọọ yọju sawọn baalẹ ni Fọtẹdo lati ki wọn kuuṣẹ ilu ni. Bi wọn ṣe ri i lọjọ yẹn ni wọn panu-pọ pe ọba awọn gan-an lo de yii. Lọjọ naa, awọn baalẹ mẹrindinlogun lo wa nikalẹ, ninu awọn bii mẹtalelọgbọn ta a ni ni gbogbo Imobi.
“Nigba ti awọn ẹbi ẹ paapaa tun fa a kalẹ, a ni ki wọn fun wa laaye lati ṣewadii nipa ẹ ka too tẹ siwaju, eyi gan-an lo mu wa ranṣẹ sawọn ọmọ wa ti wọn wa loke okun, lati mọ iru ẹni to jẹ, paapaa lori ohunkohun to ba ni i ṣe pẹlu iwa ọdaran. Awọn tọhun si fun wa lesi pe ko si iwa janduku tabi aleebu kankan lọwọ ẹ”
“Awọn ti wọn pe ara wọn ni Sons and Daughters, iyen awọn ọmọ ilu, ti wọn kọwe sileegbimọ pe awọn ko fẹ Goriọla, ko sẹni to mọ ẹgbẹ wọn yẹn tẹlẹ ni gbogbo Imobi. Awọn ni wọn n gbe iroyin kiri pe Goriọla ki i ṣe ọmọ ilu, bẹẹ ọmọ ilu si ni iya ẹ ati baba nla rẹ, iya baba wọn to jẹ ọmọ Iṣiwọ lo sọ wọn dero ibẹ.
“A sọ fun wọn pe a ko ba wọn ja, ti ẹ ba sọ pe ko ma jẹ ọba Imobi, ọba Uba gan-an lo fẹẹ jẹ tẹlẹ, awọn baalẹ ni ilẹ Imobi ni wọn lawọn fẹ ẹ, ko ṣoro, a maa mu un pada sile, ko lọọ jọba nibẹ. Ni wọn ba tun ni awọn ko ni i gba, bi wọn ṣe gbe ọrọ wa sileegbimọ aṣofin niyẹn. A difa ka too mu Goriọla, ifa ẹ si kun daadaa”
Lori awauyewuye to n lọ nipa pe ilu Iṣiwọ lo ti wa, baba oloye yii sọ pe iya to bi baba Goriọla gan-an ni ọmọ Iṣiwọ, ati pe lati kekere ni iya baba ẹ ti ko awọn ọmọ lọ siluu ọhun, eyi to fa a to fi jẹ pe ilu naa lawọn eeyan mọ baba ẹ mọ ju, atawọn ọmọ ẹ yooku, paapaa Goriola Hassan.
Awọn ti wọn gbe ẹjọ lọ sileegbimọ aṣofin naa sọrọ, ohun ti ọkan ninu wọn, Ọmọọba Sylvester Olalekan Bakare, sọ ni pe awọn ko ti i jọba ri n’Imobi, fun idi eyi, ko si ipo kankan to n jẹ ipo ọba nibẹ lasiko yii.
“Ohun ti a n sọ ni pe ki awọn aṣofin pa a laṣẹ fun Goriọla Hassan pe ko yee pera ẹ lọba ilu Imobi. Ọba kan ta a ni n’Imobi naa ni Onitasin, baalẹ la ni lawọn ilu yooku, a ko fẹ wahala rara n’Imobi, nitori ẹ la ṣe kọwe, ki wọn ba wa da a lọwọ kọ, ko yee pera ẹ lọba alade.
“Ọmọ Iṣiwọ ni gbogbo wa mọ oun ati baba ẹ si, koda a gbọ ọ ri pe baba ẹ gbiyanju lati jọba niluu Iṣiwọ. Oun paapaa, iyẹn Goriọla naa gbiyanju lati jọba nibẹ.
“ Emi o le sọ pe ki i ṣe ọmọ Uba, nitori n’Ijẹbu, ba a ṣe maa n ni ile iya la maa n ni ti baba naa, o ṣee ṣe ko jẹ ọmọ ibẹ loootọ. Pupọ ninu awọn eeyan ti wọn jẹ ọmọ Oke Imobi ni wọn tun lẹbi daadaa ni ilu Iṣiwọ ati Odosayin, fun idi eyi, o ṣee ṣe ko tan si Iṣiwọ, ko si tun jẹ ọmọ Uba.
“Ohun kan to n jọ wa loju ni pe lọdun to kọja ni Ogbẹni Goriọla yii ṣẹṣẹ wọlu wa, to sọ pe oun fẹẹ jọba. Latigba pipẹ, ọmọ ilu Iṣiwọ lawọn eeyan mọ ọn si. Ọdun Ileya lo waa ṣe lọdun to kọja, ka si too ṣẹju pẹ, o loun ni Olu Imobi, nitori ẹ la ṣe wa, ti a ni ki awọn aṣofin gba wa.
“Alaafia lawa n fẹ, ko si nnkan ti eeyan fẹẹ jẹ tabi da, ti ko ṣee ṣe, ṣugbọn o gbọdọ tẹle ilana, ohun tawọn eeyan si sọ ni pe awọn ko fẹ ẹ.”
Ẹnikan to ba wa sọrọ nibẹ lọjọ naa to ni ka forukọ bo oun laṣiiri sọ pe ki i ṣe pe Goriọla ko lẹtọọ si ori aleefa ọba, o ni o le jọba sibi to ba fẹ ninu Imobi tabi Uba.
O ni ṣugbọn irisi rẹ, bo ṣe ya tatuu sara, to tun lu eti rẹ lasiko to n fi yariini seti lo jẹ kawọn eeyan kan maa ta ko o. Ẹni naa sọ pe irisi ọkunrin yii ko jọ ti ọba alade, amuyẹ ọba si ku diẹ kaato fun un.
O fi kun un pe eyi ki i ṣe awijare fawọn igun keji ṣa, nitori tatoo ko ni i keeyan ma dije dupo labẹ ofin, ẹtọ ọmọniyan gba a laye lati dori aleefa ọba. Iyẹn lo ni o ṣe yẹ ki Goriọla yọju sileegbimọ to n pe e, ko ṣalaye ẹtọ ẹ nibẹ, ki gbogbo ohun to n run nilẹ yii si tan lọgan.