Jọkẹ Amọri
Ko din ni ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ mẹsan-an ti Kọmandi ọlọpaa to wa ni Ẹlẹyẹlẹ, n’Ibadan, foju wọn han l’Ọjọruu, ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹjọ yii, koda, akẹkọọ Poli Ibadan wa ninu wọn.
Nigba to n foju awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa han, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Ngozi Ọnadẹkọ, ṣalaye pe DPO Atiba ni olobo ta, pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kan n kora jọ lati gbe agbara fawọn iṣi mi-in, wọn si tun fẹẹ ṣeto igbaniwọle fawọn tuntun pẹlu.
O ni ẹsẹkẹsẹ lawọn ọlọpaa ti ta mọra, wọn gba ibi ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa ti n pitu ọwọ wọn lọ, wọn si ri awọn mẹsan-an ko ninu wọn.
CP Ọnadẹkọ sọ pe lẹyin ifọrọwanilẹnuwo to lagbara, awọn gende mẹsan-an naa jẹwọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ lawọn.
O ni awọn kan jẹwọ pe awọn fẹẹ gbe ipo awọn fawọn mi-in to tun tọ si ni, bẹẹ lawọn kan sọ pe ọmọ ẹgbẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ fẹẹ gba wọle lawọn.
Kọmiṣanna yii rọ awọn obi ati alagbatọ lati maa wẹyin awọn ọmọ wọn to ba wa nileewe giga wo. O ni awọn mi-in ninu awọn tọwọ ba yii jẹ akẹkọọ nileewe giga, awọn obi wọn ko si mọ pe ọwọ ti ba wọn bayii nibi ti wọn ti n ṣe ẹgbẹkẹgbẹ.
Awọn nnkan ija bii ada, aake ati ibọn lawọn ọlọpaa ba lọwọ awọn ti wọn mu yii, gbogbo ẹ naa ni wọn si tẹ kalẹ fawọn akọroyin lati ri.
Ọkan ninu awọn gende marun-un tọwọ ba naa, Ayinde Badmus, ẹni ọdun mẹtalelogun, sọ pe ọmọleewe Poli Ibadan loun.
O loun lọọ ki ọrẹ oun ni, oun ko mọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ ni, afi bawọn Amọtẹkun ṣe de lojiji, ti wọn mu oun, ṣugbọn ọrẹ oun naa sa lọ.
Ayinde tẹsiwaju pe loootọ ni wọn ba ibọn lọwọ oun, ṣugbọn ibọn naa ki i ṣe toun.
O ni ọrẹ oun to ti sa lọ lo ni ibọn ọhun, o kan jẹ pe ẹgbẹ oun ni ibọn naa wa nigba toun ati ọrẹ naa n sọrọ lọwọ ni. Bawọn Amọtẹkun si ṣe de ti wọn ri ibọn nitosi oun ni wọn mu oun.