Jọkẹ Amọri
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti fidi ẹ mulẹ pe loootọ ni baba kan, Lasisi Moshood; ẹni ọdun mẹjilelọgọta (62), pokunso nile rẹ ni Ayede-Ogbese, nipinlẹ Ondo, ati pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori ohun to mu baba naa gbe igbesẹ yii.
Obinrin kan ti wọn n pe ni Lady Evangelist Victoria Lasisi ni iyawo Oloogbe, gbajugbaja pasitọ ni wọn pe iya naa, wọn si royin pe oun atawọn ọmọ to bi fun Oloogbe Lasisi n tọju baba naa daadaa.
Ko sẹni to fura pe baba yoo gbe igbesẹ iku ọhun, iyawo atawọn ọmọ ti jade gẹgẹ ba a ṣe gbọ. Nigba ti Efanjẹliisi Victoria pada de lo kan ilẹkun titi, ṣugbọn ti ọkọ rẹ ko dahun, bẹẹ o wa ninu ile.
Nigba to pẹ ti iyawo baba yii ti n kanlẹkun ti ko gbọ idahun kankan lo yọju loju ferese, nibẹ lo ti n wo ọkọ rẹ to n mi dirodiro labẹ okun, o ti pokunso!
Awọn eeyan lo pada ja ilẹkun naa ti wọn si ba baba naa nibi to so si. Tabili atawọn ipeku kekere ti wọn n pe ni ‘stool’ ni Oloogbe naa to pọ to si gun to fi kọrun bọ okun.
A gbọ pe igi ni Alagba Lasisi fi n rin, nitori ẹsẹ n dun un, ṣugbọn awọn eeyan sọ pe eyi ko to idi kan ti baba naa yoo fi gba ẹmi ara ẹ, wọn ni ohun ti ọkọ pasitọ yii dan wo kọ sisọ.
Alaga CAN, iyẹn ẹgbẹ awọn Onigbagbọ, ẹka ti Ogbese, nipinlẹ Ondo, Pasitọ Oyedeji Aladenika, ṣapejuwee iku Lasisi bii ohun to ya ni lẹnu ju, o ni idi ti baba yii fi gba ẹmi ara ẹ ko ti i ye oun.
Alukoro ọlọpaa Ondo, DSP Funmilayọ Ọdunlami, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ. O ni iwadii tawọn n ṣe lori ẹ ti n tu aṣiri diẹdiẹ nipa ohun to mu baba ẹni ọdun mejilelọgọta yii pokunso.