Jokẹ Amọri
Gbajumọ agbẹjọro to ti figba kan jẹ kọmiṣanna fun igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Eko, to tun jẹ oludamọran lori ọrọ ofin fun ẹgbe oṣelu APC nigba kan, Dokita Muiz Banirẹ, naa ti ṣabẹwo si Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu niluu oyinbo to ti n gba itọju.
Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii ni fọto ti awọn mejeeji jọ ya gba ori ẹrọ ayelujara, ti awọn mejeeji duro ti ara wọn, ti wọn jọọ ya fọto.
Iyatọ to wa ninu fọto eleyii ati tigba ti Aarẹ Muhammadu Buhari ṣabẹwo si Tinubu ni pe Aṣiwaju ko lo ọpa bii ti asiko naa, eyi to mu ki inu awọn ololufẹ rẹ dun pe alaafia ara ti n to baba naa lọwọ, ati pe ko ni i pẹẹ pada si Naijiria, bo tilẹ jẹ pe aisan naa han lara Bọla Tinubu gan-an.
Yatọ si Banirẹ to ṣabẹwo kara o le si gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ yii, Abiọdun Faleke toun naa jẹ ọmọ ileegbimọ-aṣoju-ṣofin naa ti ṣe iru abẹwo yii kan naa si Tinubu lọsẹ to lọ lọhun-un.
Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja ni Aarẹ Buhari ṣabẹwo si oloṣelu pataki yii, ti aworan abẹwo naa si gba gbogbo ori ẹrọ ayelujara.