Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Awọn mẹrin ti ẹ n wo yii ko ta ẹpa, bẹẹ ni wọn o ta guguru, owo to lodi sofin ni wọn n ṣe. Eeyan ẹlẹran ara bii tiwọn ni wọn n pa danu, ti wọn si n gbowo ọwọ wọn, tabi ki wọn gba mọto UBER ti ẹni naa ba n wa, ki wọn si ṣa a ladaa, ko ku tan ki wọn tun dana sun oku ẹ! Ipinlẹ Ogun ni wọn ti n ṣiṣẹ ibi wọn.
Kẹhinde Saliu ti wọn n pe ni Oluọmọ ni olori wọn, awọn mẹta yooku ni Abiọdun Akinọla, Johnson Fakẹyẹ ati Jamiu Akinọla. Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ṣẹṣẹ ba wọn ni, iyẹn lẹyin ti wọn ti fi bii oṣu mẹta dọdẹ awọn eeyan naa lati ri wọn mu ṣinkun.
Ọmọbinrin kan torukọ ẹ n jẹ Aanu Salaudeen, lo mu ẹjọ lọ si teṣan ọlọpaa Onipaanu, lọjọ kejidinlogun, oṣu kẹrin, ọdun yii, pe ọga oun, Abiọdun Ọdẹbunmi, to n ṣiṣẹ POS, kuro lọfiisi awọn to wa ni Aparadija, lati lọọ ba onibaara rẹ kan ṣowo POS tawọn n ṣe.
O ni onibaara naa ti kọkọ ba ọga oun dowo-pọ pẹlu milọnu kan aabọ naira, ẹni naa lo tun ni ko gbe miliọnu mẹrin wa kawọn jọ ṣe e nilana POS, ni Oju-oore, Ọta, afi bo ṣe jẹ lati ọjọ naa lo ti nu, ti ko wale mọ. Ọmọbinrin naa sọ fawọn ọlọpaa pe bawọn si ṣe n pe nọmba rẹ to, ki i lọ.
Awọn ọlọpaa Onipaanu bẹrẹ iṣẹ itọpinpin lori Abiọdun Ọdẹbunmi to deede dawati yii, wọn si pada ri oku rẹ nibi ti wọn dana sun un si ninu ile akọku kan lagbegbe Arobiẹyẹ, l’Ọta.
Ko si apẹẹrẹ kankan ti wọn fi le mọ awọn to pa ọkunrin oni-POS yii, ṣugbọn awọn ọlọpaa naa ko sinmi. Wọn taari iwadii naa si ẹka to n gbọ ẹsun ipaniyan nipinlẹ Ogun, CSP Fẹmi Ọlabọde atawọn ikọ rẹ lẹka yii si bẹrẹ si i ṣewadii gẹgẹ bii aṣẹ ọga wọn, CP Edward Ajogun.
Iwadii naa lo gbe wọn de Ọtun-Ekiti, nitori olobo ta wọn pe ẹni to ṣiṣẹ buruku naa ti kuro l’Ọta, o ti gba ipinlẹ Ekiti lọ. Ṣugbọn nigba tawọn ọlọpaa yoo fi de Ekiti, ẹni ti wọn n wa tun ti rẹni ta a lolobo, n lo ba tun sa lọ si Ọffa, nipinlẹ Kwara.
Awọn ọlọpaa to n wa a ko kuku duro, wọn n dọdẹ ẹni naa, afigba ti wọn gbọ pe afurasi naa tun ti lọ si Bẹnnẹ, o lọọ ba wọn wo Sunday Igboho ti wọn gbe lọ si kootu.
Bẹnnẹ lo wa tawọn eeyan ti sọ asiko ti yoo kuro niluu naa fawọn ọlọpaa, n ni wọn ba lọọ duro de e, ṣinkun ni wọn si mu un laarin ipinlẹ Ogun ati Eko. Kẹhinde Saliu ti wọn n pe ni Oluọmọ ni ọdaran naa.
Nigba tawọn ọlọpaa n fọrọ wa a lẹnu wo, Kẹhinde Saliu, ọmọ Apomu, nipinlẹ Ọṣun, jẹwọ pe oun loun pa Abiọdun Ọdẹbunmi oni-POS.
O loun mọ-ọn-mọ tan an wa si Ọta, nibi ti awọn ẹlẹgbẹ oun yooku ti n duro de e pe ko gbe owo wa ni, awọn kuku ti ba a ṣowo miliọnu kan aabọ tẹlẹ. Kẹhinde sọ pe awọn ṣa ọkunrin naa ladaa pa ni lẹyin tawọn ti gbowo lọwọ ẹ, awọn si dana sun un ki ẹnikẹni ma baa le mọ bo ṣe ṣẹlẹ.
Ọkunrin apaayan naa jẹwọ pe awọn dẹrẹba ọkọ UBER, iyẹn awọn dẹrẹba ileeṣẹ aladaani ti wọn maa n lọọ gbe onibaara to ba pe wọn nile, lawọn maa n pa, pẹlu awọn oni-POS naa. O ni to ba jẹ ti dẹrẹba UBER ni, ọkan ninu awọn yoo ṣe bii ero ọkọ, yoo ni ki dẹrẹba waa gbe oun nibi kan, bẹẹ awọn ẹgbẹ rẹ yooku yoo ti farapamọ sibi kan, bi dẹrẹba naa ba de bayii, awọn yoo ṣa a ladaa pa ni, awọn yoo si gbe mọto rẹ lọ, awọn yoo lọọ ta a fun onibaara awọn.
O tun fi kun un pe oun atawọn ẹgbẹ oun tun pa ọkunrin kan torukọ ẹ n jẹ Idowu Ademiluyi, n’Itori. O lawọn ṣa a ladaa pa naa ni, awọn si gbe mọto Toyota Corolla rẹ lọ.
Kẹhinde tọwọ ba yii lo ṣọna bọwọ ṣe ba Abiọdun Akinọla, ẹni to n ra mọto awọn ti wọn ba pa lọwọ wọn. Bẹẹ naa lọwọ si ṣe ba Johnsin Fakẹyẹ l’Atan-Ọta, ati Akinọla Jamiu, l’Owode Yewa.
Mọto mẹta lawọn ọlọpaa ri gba lọwọ wọn to jẹ tawọn ti wọn ti pa, awọn mọto naa ni Toyota Camry, Toyota Corolla ati Toyota Rav 4.
Ọga ọlọpaa pata nipinlẹ Ogun, Edward Ajogun, gboriyin fawọn ọlọpaa to ṣiṣẹ takun-takun yii, eyi to fẹrẹ gba wọn to oṣu mẹta. O waa ni ki wọn ma ti i sinmi, afi ki wọn mu awọn yooku to wa nidii iṣẹ laabi yii.
Bakan naa lo rọ awọn araalu pe ki wọn jọwọ, maa sọ irin-ajo wọn fawọn ti wọn ba fọkan tan, bi ko tiẹ ju ẹni kan ṣoṣo lọ, ki wọn ṣalaye bi wọn ba ṣe fẹẹ rin fun un, paapaa to ba jẹ pe ẹni ti wọn fẹẹ lọọ ba naa ki i ṣe ẹni ti wọn mọ tẹlẹ.
Ni ti awọn apaayan yii, kootu lo ni ki wọn maa gbe wọn lọ taara lẹyin iwadii.