Lasiko to fẹẹ lọọ wọkọ baaluu ni papakọ ofuru Nnamdi Azikiwe to wa niluu Abuja ni ileeṣẹ to n ri si iwa ọdaran, ajẹbanu ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku, EFCC, nawọ gan gomina ipinlẹ Abia tẹlẹ, Theodore Orji, ni wọn ba wọ ọ lọ si olu ileeṣẹ ẹgbẹ naa. Bakan naa ni ọmọ rẹ to jẹ olori ileegbimọ aṣofin ipinlẹ naa bayii paapaa ti wa lakata awọn amunimadaa yii, wọn ni funra rẹ lo lọọ yọju si wọn.
Ṣe o to ọjọ mẹta ti EFCC ti n dọdẹ ọkunrin naa, ẹsun ikowojẹ atawọn owo kan to ṣe mọkumọku nigba to n ṣe gomina ipinlẹ Abia lọdun 2007 si 2015 ni wọn tori rẹ mu oun atọmọ rẹ, Chinedu. Biliọnu mejidinlaaadọta, owo to yẹ ko wa fun eto aabo ni wọn ṣe si wọn lọrun pe wọn ko mọ bi wọn ṣe ṣe e. Wọn ni miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹta Naira lọkunrin naa n gba loṣooṣu lasiko to fi ṣe gomina ipinlẹ Abia lọdun 2007 si 2015, ṣugbọn ko le ṣalaye ohun to fi ṣe.
Bakan naa ni wọn ni ki baba atọmọ yii waa ṣalaye owo to yẹ ki wọn fi tọju awọn wahala ti oju ọjọ, tabi ojo atawọn ajalu bẹẹ ba fa si agbegbe wọn to n lọ si bii biliọnu meji ati owo iranwọ fawọn ọdọ ti ko riṣẹ ti wọn n pe ni Sure-P tijọba apapọ gbe kalẹ.
Gbogbo owo yii ni wọn ni ekute ọlọwọ mẹwaa ji gbe lọ nipinlẹ Abia, ni wọn ba ni ki wọn waa ṣalaye rẹ.
O ti to ọjọ mẹta ti EFCC ti n dọdẹ ọkunrin naa, bẹẹ loun paapaa n lọ mọ wọn lọwọ, ko too waa di pe wọn mu un l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.