Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Nitori rogbodiyan ati aigbọra ẹni ye to n daamu wọn lẹgbẹ alatako nni, PDP, eyi to n fi ẹgbẹ naa logbologbo tawọn ọmọ ẹgbẹ kan si ti n yapa, Alaga wọn, Uche Secondus, ti wọn ni ko fipo silẹ ti sa tọ Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ lọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹjọ yii.
Nnkan bii aago mejila ọsan kọja iṣẹju mẹẹẹdogun ni Secondus de agbala Oloye Ọbasanjọ, ni OOPL, l’Abẹokuta, oun atawọn ikọ ti wọn jẹ alatilẹyin rẹ ni wọn jọ de, bo si ti de lo wọle tọ baba naa lọ, ni wọn ba bẹrẹ ipade ti wọn ko pe akọroyin si.
Ohun ti a gbọ ni pe ko sohun meji to gbe Uche Secondus delẹ Yoruba ju wahala to n ṣẹlẹ ninu PDP lọ. Ṣe awọn kan ninu igbimọ amuṣẹṣe wọn (NWC), iyẹn National Working Commitee ti kọju ija sira wọn lọsẹ meji sẹyin, ti wọn ni ki Secondus kọwe fipo alaga yii silẹ,nitori ọkan-o-jọkan ẹsun tawọn oloye ẹgbẹ fi kan an, tawọn kan ninu wọn si ti kọwe fipo wọn silẹ.
Ṣugbọn ọkunrin yii ko fẹẹ fi ipo naa silẹ, gbogbo ọgbọn to mọ lo n da lẹyin to ti sọ fun wọn lọsẹ to kọja pe oun ko nibi kan toun n lọ. A gbọ pe ki omi ma baa ti ẹyin wọ igbin rẹ lẹnu lo ṣe tun waa sa di Ọbasanjọ.
Nibi ti ọrọ ọhun ko ti i lojuuutu de, ọjọ Iṣẹgun to kọja yii lawọn aṣaaju PDP da si i lati pẹtu saawọ naa, awọn gomina PDP, awọn igbimọ alafọkantan ẹgbẹ naa atawọn eeyan wọn to wa nileegbimọ aṣofin lo da si i.
Wọn pada fẹnuko pe ki wọn kuku ṣe ipade apapọ ti wọn maa n ṣe, wọn ni ki wọn pade ninu oṣu kẹwaa, ọdun yii, lati yan adari tuntun. Koda, Gomina Nyesom Wike ti ipinlẹ Rivers, fara mọ eyi.
Ọmọ ipinlẹ Rivers ni Secondus, ọrẹ gidi si loun ati Wike tẹlẹ. Koda, bi Uche ṣe di Alaga PDP ko ṣẹyin Wike, ṣugbọn tirela oṣelu ti gba aarin awọn mejeeji, ọrẹ ọjọsi si ti di ọta ara wọn.
Lẹyin ipade ti Secondus ba baba ṣe ọhun, ọkunrin naa ba awọn oniroyin sọrọ, ohun to si sọ fun wọn ni pe ọrọ Naijiria loun ba wa, o ni bi ilu ko ṣe fara rọ lasiko yii lo mu oun wa s’Abẹokuta lati bu mu ninu omi ọgbọn Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ.
Alaga PDP naa ni Ọbasanjọ ki i ṣe ẹran ibi kan, gbogbo agbaye lo wulo fun. O ni orilẹ-ede Afghanistan to n gbona lọwọ ni baba naa lọ laipẹ yii to si pada laaye, ti kinni kan ko ṣe e. O ni idi eyi loun atawọn ikọ oun ṣe waa ba baba naa, awọn ti sọrọ nipa ijinigbe to n ṣẹlẹ ni Naijiria, atawọn iwa aburu mi-in, nitori nigba ti orilẹ-ede ba duro daadaa leeyan le ṣe oṣelu nibẹ, bi ko ba si ifọkanbalẹ, ẹgbẹ oṣelu kankan ko ṣee ṣe.
Ninu ọrọ tiẹ, Oloye Ọbasanjọ sọ pe loootọ ni Naijiria asiko yii ko fara rọ, ṣugbọn iyẹn ko tumọ si pe ko ṣee tunṣe. O ni kawọn ọmọ Naijiria gbagbe oṣelu ẹtaanu, ki wọn jọ sowọ pọ lati ri i pe orilẹ-ede yii ko tuka.