Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Aarẹ Muhammadu Buhari ti ni ki agbẹyẹwo waye lori aaye ti wọn ya sọtọ fun fifẹran jẹko lawọn ipinlẹ mẹẹẹdọgbọn lorilẹ-ede yii, kijọba le mọ bawọn to n fẹran jẹko lọna aitọ ṣe n ṣọṣẹ to.
Igbimọ kan ti yoo ri si eyi ni Buhari faṣẹ si pe ki wọn yẹ aaye ijẹko to din nirinwo (368 grazing sites) wo lawọn ipinlẹ mẹẹẹdọgbọn naa.
Amugbalẹgbẹẹ Aarẹ lori eto iroyin ati ikede Malam Garba Shehu, lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan l’Ọjọbọ, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹjọ, niluu Abuja.
O ni Ọjọgbọn Ibrahim Gambari, olori awọn oṣiṣẹ Aarẹ ni alaga igbimọ naa. Garba ṣalaye pe igbimọ naa da a labaa lati ṣe akọsilẹ aaye ijẹko yii, wọn yoo si ṣe itaniji le e lori.
O ni igbimọ naa tun dabaa pe kijọba ṣe maapu, iyẹn atọna, ti yoo maa tọka ẹka ijẹko kọọkan. Wọn waa ni bi aabo ṣe mẹhẹ to lawọn ipinlẹ ni wọn fi yan awọn ipinlẹ ti agbeyẹwo yoo kan naa.
Awọn ti wọn wa ninu igbimọ yii ni Gomina Kebbi; Atiku Bagudu, Gomina Ebonyi; David Umahi ati Minista fun ọrọ omi, Suleiman Adamu.
Awọn yooku ni Minisita eto ọgbin ati idagbasoke igberiko; Sabo Nanono. Minista eto ayika, Dokita Mohammad Mahmood, ati Igbakeji olori oṣiṣẹ, Ade Ipaye.
Igbimọ yii yoo tun dabaa pe kijọba maa ṣakọsilẹ awọn ibudo ijẹko ti ko si akọsilẹ fun, wọn yoo si ṣe onka awọn darandaran kaakiri Naijiria lapapọ. Ọjọ kẹwaa, oṣu karun-un, ọdun 2021 yii, ni igbimọ yii ṣepade akọkọ wọn gẹgẹ bi Sheu Garba ṣe wi.
Ṣugbọn ọpọ eeyan lo n bẹnu atẹ lu igbesẹ ti Aarẹ Buhari buwọ lu yii, wọn ni ete buruku lati fi toju bọ ilẹ onilẹ naa ni, ki i ṣe akọsilẹ kankan ni wọn fẹẹ tori ẹ ṣe e.