Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ijọba ipinlẹ Ogun labẹ akoso Gomina Ọmọọba Dapọ Abiọdun ti tẹwọ gba iṣi abẹrẹ mi-in to n dena arun Korona, wọn yoo si bẹrẹ si i fun awọn eeyan ilu naa lati ọsẹ tuntun yii lọ.
Kọmiṣanna eto aabo nipinlẹ Ogun, Dokita Tomi Coker, fidi ẹ mulẹ pe ẹgbẹrun kan le mẹtadinlaaadọrun-un ati irinwo le mẹrindinlọgbọn (187,426) ni onka abẹrẹ naa ti orukọ rẹ n jẹ Moderna COVID-19 vaccines to balẹ sipinlẹ Ogun lalẹ Ọjọbọ, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹjọ ọdun 2021.
Dokita Coker sọ pe pẹlu bi abẹrẹ ajẹsara naa ṣe ti de yii, ijọba ko ni i fi falẹ ko too maa fun awọn eeyan, bẹrẹ lati ẹni ọdun mejidinlogun soke lọ.
Lati fi orukọ silẹ fun gbigba abẹrẹ ajẹsara Koro yii, oju opo https:#www.vaccination.gov.ng. ni kọmiṣanna sọ pe kawọn eeyan lọ. O fi kun alaye ẹ pe ṣaaju ni ijọba Ogun ti gba awọn firiiji agbayanu ti wọn yoo maa tọju awọn abẹrẹ naa si ti ko fi ni i bajẹ, o ni wọn ti ṣeto awọn firiiji alagbara naa saaye to yẹ.
Ni gbogbo ipinlẹ Naijiria pata, ipinlẹ Ogun lo kọkọ tẹwọ-gba abẹrẹ ajẹsara akọkọ ti wọn n pe Azra Zeneca, iyẹn loṣu, kẹta ọdun 2021 yii, ti wọn si fun awọn eeyan ibẹ ni ipele akọkọ ati ikeji.
‘‘Aarin ipele kẹta aisan Korona la wa bayii, akọsilẹ si fi han pe bo ṣe paayan laarin ọsẹ mẹrin si asiko yii lọ soke si i.
“Ba a oo ṣe maa fun awọn eeyan ni abẹrẹ to de yii lati ọsẹ to n bọ lọ, a rọ wọn lati maa tẹle awọn ofin to de Korona, bii lilo ibomu deede ta a ba wa nita gbangba, fifọwọ wa deede, lilo ọṣẹ apakokoro (sanitizer) lati fi pa ọwọ wa, titakete sira ẹni ati yiyago fun awujọ ero.”
Bẹẹ ni kọmiṣanna wi.