Florence Babaṣọla
Akọwe ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun, Rasaq Ṣalinṣile, ati Alagba Lọwọ Adebiyi to jẹ alaga awọn kan ti wọn jẹ ọmọlẹyin Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, iyẹn The Osun Progressives, ni wọn ti foju bale-ẹjọ Majisreeti kan niluu Oṣogbo lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
Ẹsun igbimọ-pọ huwa buburu ati ṣiṣe akọlu si awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC meji ni sẹkiteriati ẹgbẹ wọn lọjọ kẹrinla, oṣu kẹjọ, ọdun yii, ni ileeṣẹ ọlọpaa fi kan wọn.
Bakan naa ni wọn ko awọn marun-un mi-in, ninu wọn ni kọmiṣanna tẹlẹ fun ọrọ iṣẹ-ode, Kazeem Salami, kọmiṣanna tẹlẹ fun ọrọ ere idaraya ati iṣẹ akanṣe, Biyi Ọdunlade, igbakeji olori awọn oṣiṣẹ lọfiisi gomina, Gbenga Akano, Alaba Popoọla ati Azeez Adekunle.
A oo ranti pe wahala bẹ silẹ ni sẹkiteriati ẹgbẹ APC lọjọ naa lasiko ijokoo igbimọ ti awọn alakooso ẹgbẹ lati Abuja ran wa lati gbọ ẹsun to ṣu yọ lasiko ibo abẹle ti wọn ṣe kọja.
Gẹgẹ bo ṣe wa ninu iwe ipẹjọ ti wọn fi ko awọn mejeeje wa si kootu, ṣe ni wọn gbimọ-pọ laago kan aabọ ọsan ọjọ kẹrinla, oṣu kẹjọ yii, lati ṣakọlu si Hamsat Lukman Babatunde, wọn si lẹ okuta mọ ọn lori.
Agbefọba, John Idoko, ni awọn olujẹjọ tun la aga to ti fọ mọ Ajetunmọbi Muideen lori, to si da egbo (harm) si i lara.
Idoko sọ pe iwa ti awọn olujẹjọ hu lodi, bẹẹ lo si nijiya labẹ abala ọtalelọọọdunrun o din marun-un (355) abala ikẹrinlelọgbọn ofin iwa ọdaran ti ọdun 2002 tipinlẹ Ọṣun n lo.
Lẹyin ti awọn olujẹjọ sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn ni awọn agbẹjọro wọn; Muftau Adediran ati Abdulfatai Abdusalam, rọ kootu lati fun wọn ni beeli, o ni gbajumọ ni wọn, wọn ko si ni i sa lọ fun igbẹjọ.
Adajọ Oluṣẹgun Ayilara fun Adebiyi, Ṣalinsile, Salami, Akano ati Ọdunlade laaye lati ṣe oniduuro fun beeli ara wọn (self recognition)
Ṣugbọn o gba beeli Popoọla ati Adekunle pẹlu miliọnu marun-un naira ati oniduuro kan ni iye kan naa.
Lẹyin naa lo sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹsan-an, ọdun yii.