Faith Adebọla, Eko
Agba oloṣelu ilu Eko, to tun jẹ Aṣiwaju fun ẹgbẹ oṣelu APC, Oloye Bọla Ahmed Tinubu, ti gbalejo awọn aṣofin Eko ti wọn ṣabẹwo si i niluu oyinbo lati beere alafia rẹ, wọn ni ṣaka lara baba naa da, Tinubu wa kampe.
Olori awọn aṣofin ọhun, Ọnarebu Mudashiru Ọbasa, lo ko awọn ẹlẹgbẹ rẹ mẹta mi-in sodi lati lọọ ṣe ‘ẹ n lẹ n bẹun’ si Tinubu niluu London, lorileede United Kingdom, to wa.
Ṣe lati bii ọsẹ diẹ sẹyin ni baba ẹni ọdun mọkandinlaaadọrin to ti figbakan jẹ gomina ipinlẹ Eko ti lọọ tọju ara rẹ loke-okun, latigba naa lo si ti n fara nisinmi lọhun-un.
Ninu fọto ti wọn fi lede lẹyin abẹwo yii, pẹlu ẹrin musẹ ni Aṣiwaju Tinubu fi duro laarin awọn aṣofin ọhun lati fi idunnu rẹ han si abẹwo wọn.
Awọn aṣofin mi-in to tẹle Ọbasa lọ ni Ọnarebu Nureni Akinsanya to n ṣoju agbegbe Mushin Ki-in-ni, Ọnarebu Temitọpẹ Adewale lati agbegbe Ifakọ/Ijaye ati Ọnarebu Sylvester Ogunkelu, aṣoju Ẹpẹ keji.
Bi Ọbasa ṣe wi, o ni tẹrin-tọyaya lawọn ba Tinubu, awọn jọ sọrọ, awọn si jọ fikun lukun lori bi nnkan ṣe n lọ si lorileede yii ati nipinlẹ Eko.
“Ọrọ orileede yii jẹ Tinubu logun gidi o, koko lara rẹ le. A sọrọ fun akoko to gun lori bi nnkan ṣe n lọ si lorileede yii, a si ṣakiyesi pe ko si iṣoro kan lara baba, inu rẹ dun, o si ba wa ṣawada bo ṣe maa n ṣe tẹlẹ.”
Tẹ o ba gbagbe, latigba ti Tinubu ti wa niluu eebo lawọn eeyan nla nla ti n ṣabẹwo sọdọ rẹ lati beere alaafia rẹ. Olori orileede wa, Muhammadu Buhari, gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu ati tipinlẹ Ekiti, Dokita Kayọde Fayẹmi atawọn eeyan nla nla mi-in lo ti tẹkọ leti lọ sọdọ agba ẹgbẹ All Progressives Congress, ọhun.