Florence Babaṣọla
Ṣe ni jinnijinni da bo gbogbo awọn olugbe agbegbe Oriṣa Ẹlẹjin, niluu Ikirun, nipinlẹ Ọṣun, lọjọ Aiku, Sannde, nigba ti aara ṣan pa awọn ọmọọya meji lasiko ti ojo n rọ nibẹ.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alaga ijọba ibilẹ Ifẹlodun, Hassan Ọkanlawọn, ṣalaye pe ori papa iṣere ileekeu kan ni aara naa ti ṣan pa wọn.
Ọkanlawọn ṣalaye pe Blessing lorukọ awọn ọmọ mejeeji, ọdọ iya-agba wọn ni wọn si n gbe. O fi kun un pe lati ipinlẹ Delta ni akọkọ ti wa, nigba ti ekeji wa lati ipinlẹ Ondo.
O ṣalaye pe nigba ti awọn ṣabẹwo si ile awọn ọmọ naa ni awọn gbọ pe awọn eroja ti wọn yoo fi dana ounjẹ alẹ ni wọn lọ ra nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si wọn.
Ọkanlawọn sọ siwaju pe nigba ti awọn debẹ, wọn sọ pe wọn ko ti i le gbe awọn oku mejeeji nitori o ni etutu kan ti awọn oniṣango yoo ṣe si wọn lara.