Ikun n jẹpa, Ikun n rẹdii, Ikun ko mọ pe ohun to dun a maa pa ni.
Ọmọkunrin tẹ ẹ n wo fọto rẹ yii, Edmond Kipng’etich, ti jade laye. Ọjọ ori ẹ ko ju mọkandinlogun (19) lọ, ṣugbọn obinrin ẹni ọdun marundinlogoji (35) to wa nile ọkọ lo lọọ ba lo pọ. Nibi to ti n ṣe ‘kinni’ ọhun lọwọ lọkọ iyawo ti de, niyẹn ba gun un pa nile wọn to wa ni Nakuru, lorilẹ-ede Kenya, nipari oṣu kẹjọ to tan yii.
Japheth Bil lorukọ ọkunrin to ka iyawo ẹ mabẹ Edmond yii, Judy Chelang’at si lorukọ iyawo ti ọmọde n ba sun naa.
O jọ pe olobo ti ta Japhet pe ọmọkunrin to wa niwee kẹrin nileewe girama naa n fọ iyawo oun lẹnu, eyi lo fa a to fi wale lasiko ti iyawo paapaa ko rokan rẹ, niṣe lo si ka wọn mọbi ti wọn ti n ṣere oge.
Inu buruku bi Japheth, ida ni wọn lo fa yọ, ko si lo o fẹlomi-in ju ọmọde to n ba ẹgbẹ iya rẹ sun naa lọ, o gun un yanna-yanna.
Agbẹnusọ ọlọpaa, Kuresoi DCIO, Peter Obonyo, fidi iṣẹle yii mulẹ.
O ni Edmund ko ku lẹsẹkẹsẹ latari ida ti ọkọ iyawo gun un. O ni ọmọkunrin naa raaye sa jade pẹlu ọgbẹ oriṣiiriṣii lara rẹ, awọn ẹlẹyinju aanu si sare gbe e lọ sọsibitu Olenguruone, awọn iyẹn ko gba a, ni wọn ba tun sare gbe e lọ sọsibitu kan ti wọn n pe ni Rift Valley General Hospital, ibẹ lo si ti jẹ Ọlọrun nipe, to ku patapata.
Awọn ọlọpaa ti n wa Japheth to gun un pa bayii, wọn ko ti i ri, nitori wọn ni nigba to ti di pe wọn gbe ọmọ naa lọ sọsibitu loun ti na papa bora. Home