Stephen Ajagbe, Ilọrin
Lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii lawọn adigunjale kan ti wọn to bii marun-un ya bo ile itura Stadium Hotel, to wa lọna Sultan, niluu Ilọrin, nibi ti wọn ti yinbọn fun maneja ile-itura naa atawọn meji kan.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Ajayi Ọkasanmi, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, ṣalaye pe awọn mẹtẹẹta ti wa nilewosan, nibi ti wọn ti n gba itọju. O ni ko sẹni to ku ninu akọlu naa.
Ọkasanmi ni ileeṣẹ ọlọpaa ti n ṣakitiyan lati ri awọn ọdaran naa mu, o sọ pẹlu idaniloju pe ọwọ yoo tẹ wọn laipẹ.
Ẹnikan tiṣẹlẹ naa ṣoju ẹ ṣalaye fun akọroyin wa pe ni nnkan bii aago mẹsan-an ku ogun iṣẹju lawọn ọdaran naa de ninu aṣọ dudu, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn soke.
Onitọhun ti ko fẹ ka darukọ rẹ ni gbogbo awọn tawọn wa nibẹ lawọn sa kijokijo nigba tawọn gbọ iro ibọn.
O ni inu ile-igbọnsẹ lawọn sa pamọ si titi tawọn ole naa fi pa itu ọwọ wọn tan, ti wọn si fẹsẹ fẹ ẹ.
Gbogbo dukia awọn onibaara bii foonu, owo atawọn nnkan mi-in lo ni wọn gba lọ.
Ọkunrin yii ni nigba tawọn maa jade latinu tọilẹẹti tawọn sa pamọ si, awọn ba ẹni kan nita ninu agbara ẹjẹ, awọn tun ri maneja otẹẹli naa ti wọn ṣe leṣe.
Ilewosan jẹnẹra tilu Ilọrin lawọn si ko wọn lọ fun itọju.