Faith Adebọla
Ibaa jẹ nipa lilo foonu ni o, abi lilo awọn eroja ibanisọrọ bii okun ti wọn n ki seti, tawọn eleebo n pe ni ****handsfree, bo si jẹ nipasẹ eyi ti wọn n pe ni bluetooth naa ni, ijọba ni eyi yoowu ko jẹ, awakọ to ba n gba ipe loju popo lasiko to n wakọ maa fi ẹwọn oṣu mẹfa jura bii awada ni.
Ọgbẹni Bisi Kazeem ti i ṣe ọga agba lẹka idanilẹkọọ ti Ajọ ẹṣọ oju popo, FRSC (Federal Road Safety Commission) lo yan-na-na ọrọ yii ninu ifọrọwanilẹnuwo kan tiweeroyin Punch ṣe fun un, lọjọ Abamẹta, Satide.
Kazeem ni ajọ Road Safety, bi wọn ṣe saaba maa n pe wọn, ko ni i gba oju bọrọ fẹnikẹni lori ofin yii, atawọn ofin mi-in to yẹ kawọn onimọto pa mọ nirona, paapaa lasiko ti a ti wọnu oṣu ba-ba-ba yii, ti ọdun si ti n lọ sopin.
O ni lọpọ igba lawọn ti fi pampẹ ofin gbe awọn onimọto latari pe wọn n gba ipe nigba ti wọn n wakọ lọwọ, ṣugbọn awawi ti ọpọ wọn maa n sọ ni pe bluetooth ati earpods lawọn n lo, awọn kan n fẹnu sọrọ feti gbọrọ lasan ni, ko di awọn lọwọ wiwakọ daadaa.
“Ṣugbọn awawi lasan ni, ohun ti ofin sọ ninu iwe ofin irinna (National Road Traffic Regulations) tijọba apapọ ṣe lọdun 2012, labẹ isọri kẹrindinlaaadọsan-an (166) abala kin-in-ni, pe ohunkohun ko gbọdọ pin ọkan awakọ niya, o si lodi lati gba ipe, dahun ipe tabi fesi si ipe lasiko teeyan n wa ọkọ lọwọ. Ohun to bojumu ni keeyan da ọkọ wiwa duro, ko paaki, ko gba ipe to fẹẹ gba, ko si tun maa ba irinajo rẹ lọ.
‘‘Yatọ si gbigba ipe, a maa n rọ awọn awakọ lati ma ṣe maa paarọ kasẹẹti, CD tabi ki wọn lawọn n yi ẹrọ redio inu mọto wọn lati teṣan redio kan si omi-in, tori ọpọ ijamba ojupopo lo ti ṣẹlẹ latari iwa aibofinmu bẹẹ.
‘‘Lati asiko yii lọ, Ajọ Road Safety yoo ri i daju pe awọn awakọ pa awọn ofin wọnyi mọ, tabi ki awọn to ba tasẹ agẹrẹ fimu kata ofin bo ṣe yẹ.”