Florence Babaṣọla
Ninu ipinnu rẹ lati ma ṣe faaye gba iwa ṣiṣe awọn akẹkọọ-binrin baṣubaṣu, hihalẹ mọ awọn akẹkọọ ati fifipa mu awọn akẹkọọ ṣe nnkan ti wọn ko fẹẹ ṣe, Fasiti Ifẹ ti fi ọwọ osi juwe ile fun olukọ rẹ kan, Dokita Mosọbalaje.
Ninu ipade igbimọ awọn oluṣakoso fasiti naa to waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni wọn ti fẹnu ko pe ki Dokita Adebayọ Mosọbalaje maa lọ sile.
Ninu atẹjade kan ti Alukoro fasiti naa, Abiọdun Ọlarewaju, fi sita lo ti sọ pe ẹka ti wọn ti n kọ nipa imọ ede oyinbo ni Mosọbalaje ti n ṣiṣẹ.
Ọlarewaju ṣalaye pe awọn igbimọ ṣagbeyẹwo oniruuru ẹsun ti wọn fi kan olukọ yii, bẹẹ ni wọn tun ṣewadii daadaa lori ẹ, o si han gbangba pe o jẹbi. Ko baa le jẹ ẹkọ fun ẹnikẹni to ba tun fẹẹ ṣan aṣọ iru rẹ ṣoro, lo jẹ ki wọn le e danu.