Akẹkọọ ileewe girama Naburereya, lorilẹ-ede Kenya, ni Joan Wekesa, ọmọbinrin ẹni ọdun mọkanlelogun ni. Afi bi wọn ṣe lo lọọ sun sile ọrẹkunrin rẹ mọju lọsẹ to kọja yii, ti iya rẹ si ba a wi pe ọmọ ire ki i ṣe bẹẹ, ti ọmọge naa si binu pokunso.
Ki i tilẹ i ṣe ile awọn obi rẹ lo pokunso si, ile ọrẹkunrin rẹ naa lo binu pokunso si lẹyin ti iya rẹ ba a wi.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, iwe keji lọmọbinrin to pa ara ẹ yii wa nileewe girama, ọjọ ori rẹ ti ju kilaasi ọhun lọ, iyẹn lo si fi yẹ ko kọju mọ iwe rẹ gẹgẹ bi awọn obi rẹ ṣe n ba a wi, ṣugbọn ọmọ naa ti jaju oge, o si ti ni ọkunrin kan laye rẹ ti ko jẹ ki alaye awọn to bi i wọ ọ leti mọ.
Lọjọ tiṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, iya rẹ, Abilekọ Wekesa Praxidese, ṣalaye pe ileewe lo yẹ kọmọ oun wa, ẹnikan lo ta oun lolobo pe ko si nileewe, niṣe lo lọọ sun sile ọrẹkunrin ẹ nitosi ọja Kabula, ni Kenya.
O ni oun gba ile ọkunrin naa lọ, oun si ba ọmọ oun nibẹ loootọ. O loun beere lọwọ ẹ pe ki lo n ṣe lọdọ ọkunrin nigba to yẹ ko wa nileewe, iya yii ni ọmọ oun ko dahun, niṣe lo n wo oun bii ori ẹran. Eyi lo jẹ koun pada lọ sile lati lọọ pe baba rẹ wa.
Iya Joan ni afi bawọn ṣe dele naa pada to jẹ oku ọmọ awọn lawọn ba to n mi dirodiro lori okun, to ti ku.
Iya rẹ ni ko ṣẹṣẹ maa halẹ mọ oun toun ba ba a wi, o ni Joan yoo sọ pe boun ko ba fi oun silẹ, oun yoo pa ara oun lọjọ kan, nigba naa loju awọn obi oun yoo ja a.
Mọṣuari ni wọn gbe Joan lọ, ko tun si ohun kan ti wọn le ṣe si ọrọ ọmọge to binu ku naa mọ.