Gbigba owo-ori lori ọja (VAT) dofin l’Ekoo, Sanwo-Olu ti buwọ lu u

Faith Adebọla

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, ti buwọ lu abadofin lori gbigba owo-ori lori ọja tawọn eleebo n pe ni Value Added Tax (VAT) nipinlẹ Eko, eto naa si ti dofin tijọba Eko yoo maa lo lẹyẹ-o-sọka.

Atẹjade kan latọwọ Kọmiṣanna feto iroyin, Ọgbẹni Gbenga Ọmọtọshọ, lo fidi eyi mulẹ lọjọ Ẹti, Furaidee yii.

Atẹjade naa ka pe: “Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ti buwọ lu abadofin to fun ipinlẹ Eko lagbara ati aṣẹ lati bẹrẹ si i gba owo-ori lori ọja, VAT, nipinlẹ Eko, gẹgẹ bawọn aṣofin Eko ṣe pinnu rẹ, ti wọn si fontẹ lu u.

Gomina sọ abadofin naa di ofin to maa bẹrẹ iṣẹ nipinlẹ Eko, ni nnkan bii aago mejila ku iṣẹju mẹẹẹdogun owurọ ọjọ Ẹti, Furaidee, bo ṣe n dari de lati ilu Abuja to lọ.

Ofin VAT yii fun ipinlẹ Eko laṣẹ lati maa gba owo-ori ọja funra wọn ati si apo ijọba ipinlẹ Eko.

Pẹlu ibuwọlu yii, ofin VAT ti di mimuṣẹ jake-jado ipinlẹ Eko, ofin naa si ti bẹrẹ iṣẹ lẹsẹkẹsẹ,” bi atẹjade naa ṣe wi.

Tẹ o ba gbagbe, ọsan Ọjọbọ, Tọsidee, lawọn aṣofin Eko fontẹ lu abadofin naa, ti wọn si taari rẹ sọfiisi gomina fun ibuwọlu rẹ, lati sọ ọ di ofin ti wọn yoo maa mu lo nipinlẹ naa.

Leave a Reply