Faith Adebọla
Ayọ ati idunnu ijọba ipinlẹ Rivers lori ọrọ owo-ori ọja VAT, atawọn ijọba ipinlẹ mi-in ti wọn fẹẹ ṣe bii tiwọn, ti fọwọ rọ igi igbagbe na, pẹlu bile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun kan ṣe paṣẹ lọjọ Ẹti, Furaidee yii, pe ẹnikẹni ko gbọdọ gba owo-ori ọja ti wọn n pe ni VAT (Value Added Tax) nipinlẹ ọhun, titi tile-ẹjọ naa yoo fi ṣagbeyẹwo ẹjọ to wa niwaju wọn, ti wọn yoo si gbe idajọ kalẹ.
Adajọ Haruna Simon Tsanami lo paṣẹ yii ninu ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun kan ti ẹka ileeṣẹ ijọba apapọ to n gba owo-ori, FIRS (Federal Inland Revenue Service) pe ta ko idajọ ile-ẹjọ giga to fun ipinlẹ Rivers laṣẹ lati maa gba owo-ori ọja naa.
Adajọ Haruna tun paṣẹ pe ki Gomina ipinlẹ Rivers, Amofin Nyesom Wike, ati awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ rẹ ṣi dawọ duro na lori ofin tuntun tileegbimọ aṣofin ṣẹṣẹ ṣe ti gomina naa si ti buwọ lu, o ni ki wọn ma ti i bẹrẹ si i lo ofin ọhun, ki wọn si dawọ duro na.
Ṣugbọn ki i ṣe ipinlẹ Rivers nikan o, ile-ẹjọ naa tun paṣẹ pe kawọn oṣiṣẹ agbowoori tijọba apapọ, FIRS, naa ṣi lọ mu suuru, tọtun-un tosi wọn ko gbọdọ gbowo VAT lọwọ ẹnikẹni lasiko yii na.
Adajọ naa ni idi meji loun fi paṣẹ yii, idi akọkọ ni pe ojooro lo maa jẹ fun olupẹjọ ati olujẹjọ nigba tawọn mejeeji ti ko ẹjọ wọn dewaju ile-ẹjọ, ti ọkan lara wọn si n ba iṣẹ lọ lori ohun ti wọn pẹjọ le lori, o ni’ru nnkan bẹẹ ko ba ilana idajọ ododo mu.
Idi keji ni pe, adajọ naa loun ti ri iwe ibeere kan gba latọdọ ijọba ipinlẹ Eko lori ẹjọ yii, ijọba ipinlẹ Eko beere pe kile-ẹjọ gba awọn laaye lati wa lara awọn olujẹjọ to maa koju olupẹjọ lori ọrọ yii, pe ẹjọ naa kan ipinlẹ awọn gbọngbọn, awọn si fẹẹ dara-pọ mọ ipinlẹ Rivers lati ro arojare lori ẹjọ naa.
Latari ibeere yii, Adajọ ni o pọn dandan foun lati fun wọn laaye ki wọn di ọkan lara awọn olujẹjọ, ki wọn si ko awọn ẹri, iwe, akọsilẹ ati alaye wọn ṣọwọ siwaju ile-ẹjọ.
Ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun naa, ti nọmba rẹ jẹ CA/PH/282/2021 ni ilẹ-ẹjọ naa paṣẹ pe awọn ti sun igbẹjọ siwaju, o di ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹsan-an, ti igbẹjọ too bẹrẹ ni pẹrẹwu.