Faith Adebọla
Awuyewuye nipa ofin owo-ori ọja ti gba ọna mi-in yọ, Gomina ipinlẹ Rivers, Amofin Nyesom Ezewo Wike, ti kọri sile-ẹjọ to ga ju lọ, lati ba wọn foju agba ati oju ofin wo ọrọ to n ja ranyin nilẹ ọhun, ki wọn si gbe idajọ kalẹ lori ẹni to lẹtọọ si gbigba ati nina owo naa.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, nijọba ipinlẹ Rivers lọọ kọwe ẹsun rẹ sile-ẹjọ giga ju lọ ọhun, eyi to fikalẹ siluu Abuja, olu-ilu ilẹ wa.
Ninu iwe ẹsun ọhun, Gomina ipinlẹ Rivers ni kile-ẹjọ ba awọn wo aṣẹ tile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun pa niluu Abuja lọsẹ to kọja pe kawọn iha mejeeji to n ja si ọrọ VAT yii ṣi lọọ simẹdọ na, ki kaluku lọọ wabikan jokoo si lori ọrọ ohun na, ki nnkan si maa lọ bo ṣe wa ṣaaju kile-ẹjọ giga kan too gbe agbara wọ ipinlẹ Rivers lati maa gba owo naa.
Latari idajọ ile-ẹjọ giga ọhun, ijọba ipinlẹ Rivers ati tipinlẹ Eko ti ṣofin lati bẹrẹ si i gba owo-ori ọja ti wọn n pe ni Value Added Tax (VAT) naa lawọn ipinlẹ wọn, ofin naa si da ijọba apapọ ati ileeṣẹ agbowoori wọn, Federal Inland Revenue Service (FIRS) lọwọ kọ, awọn ni wọn ti n gba owo-ori naa latẹyinwa, ti wọn n fi i ṣọwọ sapo ijọba apapọ l’Abuja.
Ṣugbọn aṣẹ tile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun pa lọsẹ to kọja ti fa ọpọ awuyewuye lori ọrọ yii, bawọn amofin ati ọjọgbọn kan ṣe n sọ pe aṣẹ naa ko kan ofin tawọn ipinlẹ mejeeji ṣẹṣẹ ṣe lati maa gba owo-ori naa, awọn mi-in sọ pe aṣẹ naa ti tun gbe agbara wọ ajọ FIRS lati maa ṣe bi wọn ṣe n ṣe bọ latilẹ.
Ọrọ yii lo mu kipinlẹ Rivers kọri sile-ẹjọ to ga ju lọ lọtẹ yii, ki wọn le ba wọn yanju ọrọ naa, ki gbogbo gb’odo-n-ro’ṣọ ọrọ yii le r’odo lọọ mumi.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, nireti wa pe igbẹjọ yoo tẹsiwaju nile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun, ọjọ naa ni wọn sun igbẹjọ to kan si tẹlẹ, ṣugbọn ile-ẹjọ to ga ju lọ ko ti i mu ọjọ ti wọn yoo bẹrẹ igbẹjọ lori iwe ẹsun tipinlẹ Rivers ṣẹṣẹ kọ wa yii.