Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu, ti ni digbi loun ṣi wa lori ofin to de kiko ẹran jẹ nita gbangba nipinlẹ Ondo ati pe oun ko ṣetan ati boju wẹyin rara lori ipinnu naa.
Gomina sọrọ yii lasiko to n gba alejo awọn agba iranṣẹ Ọlọrun kan lati inu ijọ Deeper Life lọfiisi rẹ to wa ni Alagbaka niluu Akurẹ lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
Aketi ni oun mọ daju pe ofin tuntun ọhun pẹlu akitiyan ẹsọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo ko fi bẹẹ dun mọ awọn eeyan kan ninu, ṣugbọn ko sohun ti wọn le ṣe lori rẹ nitori pe oun ti mura tan lati daabo bo awọn eeyan ipinlẹ Ondo lọnakọna.
O ni asiko ti to fawọn agbẹ lati lọọ maa ṣiṣẹ wọn lai si ibẹru pe ẹnikan n bọ waa fi maaluu ba ire oko wọn jẹ tabi ki wọn ji wọn gbe gẹgẹ bii ti ayẹyinwa.
O ni ko soootọ ninu ohun tawọn eeyan kan n sọ kiri pe ijọba ṣe agbekalẹ ofin naa nitori awọn ẹya kan pato, igbesẹ ifi ofin de naa lo ni o waye fun idagbasoke ati igbe-aye alaafia awọn araalu.
Lẹyin eyi lo rọ awọn pasitọ ọhun lati maa gbadura fun oun atawọn ẹsọ Amọtẹkun gidigidi ki gbogbo ero ati akitiyan awọn onisẹ ibi lori iṣejọba rẹ le ja si asan.