Makinde le ọkan ninu awọn kọmiṣanna rẹ danu

Lẹyin wakati diẹ ti o ti igbele Korona de, Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti le Kọmiṣanna fun iṣẹ ode, Ọjọgbọn Rapheal Afọnja, danu.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe gomina lori eto iroyin, Ọgbẹni Taiwo Adisa, fọwọ si lo ti ṣalaye pe lẹta naa paṣẹ pe ki kọmiṣanna naa fi ipo rẹ silẹ loju ẹsẹ, ko si ko gbogbo dukia ijọba to ba wá lọwọ rẹ silẹ fun akọwe agba nileeṣẹ to n ri si iṣẹ ode, awọn ohun amayedẹrun ati eto irinna.

Ninu lẹta ọhun ni wọn ti dupẹ lọwọ Afọnja fun iṣẹ takuntakun to ṣe nigba to wa nipo.

Bakan naa ni gomina tun mu ayipada ba ileeṣẹ ti awọn kọmiṣanna meji kan ti n ṣiṣẹ tẹlẹ. Awọn tọrọ kan ni Kọmiṣanna fun Iṣẹ Akanṣẹ, Oloye Bayọ Lawal, ti wọn gbe lọ si ileeṣẹ to n ri si ọrọ oye jijẹ ati ọrọ alaga ijọba ibilẹ nipinlẹ Ọyọ. Bakan naa ni ayipada de ba ipo Arabinrin Oriṣadeyi to ti wa nileeṣẹ awọn lọbalọba tẹlẹ pada si ileeṣẹ to n ri si awọn iṣẹ akanṣe.

Akọwe ijọba, Abilekọ Olubamiwo Adeọṣun, sọ pe lẹyẹ o sọka ni ọkunrin yii gbọdọ fi ipo silẹ. Bẹẹ ni ki awọn ti wọn paarọ ipo wọn yii naa bẹrẹ iṣẹ ni aaye tuntun yii loju ẹsẹ.

Ko sẹni to ti i le sọ ohun to fa igbesẹ gomina lori ọrọ kọmiṣanna ti wọn le danu yii. A gbọ pe Ọjọgbọn Afọnja ti wa ni igbele Korona fun ọsẹ diẹ. Ni kete to si pada de ni gomina fọwọ osi juwe ile fun un yii.

 

Leave a Reply