Nitori papakọ ofurufu atawọn nnkan mi-in, gomina Ogun fẹẹ ya biliọnu mẹtalelọgọrin-aabọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, ti beere fun ẹyawo biliọnu mẹtalelọgọrin ataabọ(83.5bn) lọwọ ajọ kan ti wọn n pe ni Revenue Mobilisation Allocation and Fiscal Commission (RAMFAC). Iyẹn ajọ to n ri si pipin owo fun ẹka ijọba mẹtẹẹta.

Igbedide papakọ ofurufu akẹru to wa ni Remọ, idagbasoke eto ọgbin, eto igbafẹ, aṣa atawọn nnkan alumọọni ti Ọlọrun fi jinnki ipinlẹ Ogun ni gomina  sọ pe owo naa yoo wa fun, yoo si tun pese iṣẹ lẹka kọọkan fun ọpọlọpọ eeyan ipinlẹ yii.

Ọjọ Iṣẹgun,Tusidee, ọjọ kẹrinla, oṣu kẹsan-an yii, ni Gomina Dapọ Abiọdun sọ igbesẹ ẹyawo yii di mimọ, nigba to gbalejo ikọ RAMFAC ati alaga wọn, Adamu Dibal, niluu Abẹokuta.

Gomina ṣalaye pe bi ajọ yii ba le ya ipinlẹ Ogun lowo naa, toun lo o fun papakọ ofurufu akẹru ọhun, aaye idokowo nla ni yoo jẹ fun ẹkun Iwọ-Oorun Afrika, yoo si pese iṣẹ gidi.

O fi kun un pe ẹka ọgbin, nnkan alumọọni, irin-ajo afẹ atawọn mi-in yoo tun goke agba si i pẹlu ẹyawo yii, bẹẹ ni ipinlẹ Ogun yoo tun ni anfaani lati gbilẹ si i labala to ti n pawo wọle.

Nigba to n ṣalaye siwaju si i, Gomina Abiọdun sọ pe ipinlẹ Ogun lo ni igbo ọba to n pawo wọle ju ni Naijiria. O ni ipinlẹ yii ni igbo obi, kòkó, ọ̀pẹ ati rọba. Bẹẹ naa lo si jẹ pe ipinlẹ Ogun lo n pese paki ati awọn nnkan ọsin oniyẹẹ ju lọ lorilẹ-ede yii.

Alaga ajọ RAMFAC, Adamu Dibal, ṣalaye pe awọn waa bẹ ipinlẹ Ogun wo gẹgẹ bii ara eto to yẹ kawọn ṣe kowo naa too bọ sijọba lọwọ ni.

O ni inu oun dun pe ipinlẹ Ogun ni awọn nnkan amuṣọrọ to le jẹ kawọn olokoowo waa ba wọn dowo-pọ, awọn yoo si ṣiṣẹ tọ bi yoo ṣe bọ si i.

Leave a Reply